GBAJUMO

AWON ILE IGBIMO ASOFIN EKO TI WON TUN KOLU AMBODE *WON TI SO PE OJU AYE NI WON N SE



O fe to otaleloodunrun (350) omo egbe akole-kodoti, ti oruko won je PSP l’Ekoo ti won ya lo sile Asiwaju Bola Tinubu, gomina ipinle Eko tele ninu osu kerin odun yii, ohun ti won si lo so lojo naa ni pe, Gomina Ambode ti gba ounje lenu awon, ati pe idoti repete lokunrin naa fe fi ba Eko je bayii.
Bola Tinubu ba won soro lojo naa, bee lo seleri pe oun yoo ba gomina naa soro, ati pe oun yoo wa bi awon omo ile igbimo asofin Eko pelu gomina naa yoo se jokoo wa ojuutu soro ohun.
Nibe lojo naa ni Asiwaju oloselu yii ti so pe oun ko mo nipa ileese ohun o, ati pe awon ti won n so pe oun loun ni ileese Visionscape, iro ni won fi pa mo oun.
Asaaju egbe oselu APC lojo naa wa ro Gomina Ambode wi pe, ti eto kole-kodoti tuntun to gbe wole, iyen Vision scape ko ba so eso rere, paapaa lori bi gbogbo awon araalu se n pariwo, Bola Tinubu ti so pe ko gbe itiju ta, ko gbe ise pada fawon to n se e tele. O ni, ti nnkan ko ba baje, ko nilo ki eeyan maa so pe oun fe tun nnkankan se.”
Boro ohun se wa niyen o, lasiko igba naa lohun-un siybgbon ni bayii, ile igbimos asofim Eko ti pase wi pe ki ileese PSP pada sigboro ki wlon maa ba ise won lo.
Boro se ri nigba naa niyen ti enikeni ko si gbo nnkankan mo, paapaa awon ti won sewode lo fehonu han lodo Tinubu. Sugbon lana-an ni iroyin gbalu wi pe, ile igbimo asofin ti da eto Visionscape ru mo Ambode lowo, won ti pase ki PSP pada sigboro, ki won maa ba ise won lo.
Abenugan-an ile igbimo asofin Eko, Mudashiru Obasa lo pase ohun loruko awon mokandinlogoji (39) mi-in ti won jo wa nile igbimo. O ti ni ki ileese PSP bere ise pada, bee ni won ti yora won lori igbese ti Gomina Ambode gbe lori bo se gbe ise kole-kodoti l’Ekoo fun ileese Visionscape. Won ti lawon ko mo nipa e, ati pe igbese ti gomina ohun gbe, won lo fi da wahala sile ni, nitori opo ni eeyan ni ise bo lowo won, ti gbogbo Eko tun kun fun panti ati idoti loju popo ati kaakiri igboro.
Ile igbimo asofin Eko ti wa ke si kominsanna feto ayika, Babatunde Durosinmi Etti ki o tete wa salaye boro ohun se je, bee ni won ti pase ki awon PSP pada sigboro, ki won tete maa ba ise won lo.
Lojuese ti iroyin yii gba igboro kan lorisirisi aroye ti tele e. Bi awon eeyan kan se bu enu ate lu ohun ti awon asofin Eko se, bee lawon mi-in tun yin won wi pe, loooto lo ye ki PSP pada senu ise nitori oorun ati idoti buruku ti fe ba Eko je bayii.

Okunrin kan lori redio laaaro yii, okan lara awon to maa n se atupale iwe iroyin to n jade lojoojumo so pe, “Igbese awon asofin yii fii han wi pe Ambode ko lenu mo l’Ekoo ni, kilode ti won ko pase ti won pa yii tele. Nisinyi, ti gomina yii ko pada mo, to je pe elomi-in ni yoo bo sori ipo agbara, iyen gan-an lo fa a ti Ambode se di agbele-he, okunrin naa ko nitumo sawon eeyan bii gomina mo. Bi eni ti ko si lori ipo gan-an mo loro e da bayii. Se e ri awon eeyan wa, oju aye ti poju fun won, nigba ti gomina yen si lase lenu daadaa, kilode ti won ko pase ki PSP pada si titi, ki visionscape maa lo? Emi o so pe igbese yen ko dara o, sugbon pelu ariwo tawaon araalu ti n pa latijo yii lori oorun to gba igboro kan, kilode ti won ko ti gbe igbese ohun tipe.?
O ni, "Ohun to buru jai ni bi ile igbimo asofin Eko se so pe awon ko mo nipa ileese kole-kodoti ti Ambode gbe wa. Fun odidi odun meta ki won so pe awon ko mo, oju aye lo n se won, bee irufe iwa bee ko ye fawon asofin. Ohun ti won si n so fun wa ni pe, awon paapaa enu won ko tole l'Ekoo ni, nitori ti gomina yen ko ba nisoro lati pada a ni, gbogbo won ni won yoo si maa se baba ke e pe fun un, sugbon nigba toro ti ri bo se wa nisinyi fun Ambode, ko si ara ti won ko ni i fi okunrin naa da. Bee owo repete ni ijoba Eko ti na lori Visionscape, se o ye ko ri bee? 
Elomi-in ni tie so pe, o dara bee, lara ohun to koba gomina yen niyen, ko dara ki eeyan dori ipo ki o maa ba ise to ba nile je tabi ko loun yoo pa a ti, irufe nnkan to maa n sele nigbeyin niyen. Mo ki awon PSP ku oriire, sugbon ki awon naa sise won daadaa ki idoti ati panti to le fa aisan buruku l’Ekoo le dohun igbagbe.”


Post a Comment

0 Comments