Loni-in ojo kerindilogun osu kefa odun 2018 ni itan mi-in
tun sele l’Ekiti, bi won se n bura fun gomina tuntun, John Kayode Fayemi, bee
ni ajo EFCC tewo gba Peter Ayodele Fayose niluu Abuja.
Okan di gomina, ikeji kuro nipo gomina, bee lo di alejo nla lodo
ajo EFCC lati dahun awon ibeere to ni se pelu iwa ajebanu atawon iwa odaran
mi-in.
Laaro kutu lawon eeyan ti n wo lo si gbongan nla Ekiti
Parapo Pavillion niluu Ado-Ekiti nibi ti won ti bura fun Kayode Fayemi, gege bi
gomina tuntun nipinle naa.
Bi okunrin oloselu yii ti bo sori apere nibi ti ero agbagbe,
iyen microphone wa, ohun akoko to koko so fawon eeyan ipinle Ekiti ni pe, lati
wakati yii lo, igba otun ti de.
Lowo asale, ninu alaye to se lori ero amohunmaworan Channels
television lo ti so pe, oun ti setan lati sise takuntakun lori bi ise agbe yoo
se ni ilosiwaju nla nipinle naa.
Kayode Fayemi so pe, gbogbo ona ti ise agbe yoo gba fi wulo
fun ati olori ati elemu nipinle naa ni ijoba setan bayi lati mojuto.
Siwaju si i, o ni lori ise agbe ti oun n so nipa e yii, awon
odo paapaa ni ise gidi lati se, ti ara yoo si tu kaluku.
Ohun mi-in ti gomina ohun tun menuba ni eto eko to yanranti,
o ni ijoba oun yoo mojuto oro eko, ti Ekiti yoo pada si aaye pataki to wa ti a
ba n so nipa eto eko gidi ni Nigeria. Ohun mi-in ti gomina yii tun loun yoo
sise le lori ni bi owo osu awon osise yoo se te won lowo, paapaa eyi ti ijoba
to sese ko gba wole je won. Bakan naa lo so pe, ijoba naa ko ni i fowo yepere
mu owo osu won nipinle naa.
Siwaju si i, Fayemi tun so pe, ti ijoba ba n ri owo osu san
deede, eyi gan-an lo le mu awujo tete dagbasoke, nitori owo ti won ba n gba naa
ni yoo maa mu oro aje ru gogo si i, ti ara yoo de kaluku laarin ilu.
Bakan naa lo tun so pe ise takuntakun nijoba oun yoo se lori
oro ilera araalu, ati pe awon ohun amayederun lorisirisi yoo je ohun amojuto
gidi fun idagbasoke ipinle Ekiti.
Te o ba gbagbe, igba keji ree ti gomina tuntun yii yoo pada
sile ijoba ni Ado Ekiti. Odun 2014 ni Ayodele Fayose fidi e janle lasiko to gbiyanju
lati dije ko le ba a sejoba ipinle ohun leekan si i, sugbon nise ni ibo ti won
di lodun naa lohun-un ko se e loore rara.
Ni bayii to ti pada sile ijoba, o ti so pe igbe aye irorun
alailegbe ni ki awon omo Ekiti maa reti bayii.
Sa o, bi Fayemi se n wole so o sile ijoba l’Ado-Ekiti, ninu galo
awon EFCC ni Fayose wo lo ni tie. Okan bo sipo gomina, ikeji kuro nipo gomina,
ileeese to n sewadii awon to ba kowo ilu je tabi huwa odaran mi-in; lodo won
gan an ni Fayose gba lo. Nibi ti gbogbo oro yii yoo yori si, e o maa ba a pade
lori ikanni yii.
0 Comments