Awon omo egbe oselu PDP nijoba ibile meje ti ekun idibo Guusu ipinle Kwara
(Kwara south) ti panupo fowo si i ki pe gomina ipinle naa, Abdul-Fatah Ahmed jade
dupo seneto lodun 2019.
Niluu Omu-Aran nibi ti eto
idibo ohun ti fe waye lawon asoju egbe kaakiri ijoba ibile mejeeje ohun lekun
idibo naa ti panupo so pe Gomina AbdulFtah Ahmed, eni tawon eeyan tun maa n pe
ni Megida lagbo oselu lawon fowo si ko jade fun ipo seneto lati soju agbegbe
naa niluu Abuja.
Ni bayii, ohun to foju han ni
pe, ilu Abuja nile igbimo asofin agba ni gomina yii yoo dari si, iyen to ba
jawe olubori ninu eto idibo ti yoo waye lodun 2019.
Ni
nnkan bi odun meedogun seyin, iyen 2003 ni Abdul Fatah Ahmed darapo mo oselu
ipinle Kwara lasiko ti Dokita Bukola Saraki de ipo gomina.
Okunrin
oloselu omo ilu Shaare nijoba ibile Ifelodun yii ni komisanna feto isuna owo
ati idagbasoke oro aje laarin odun 2003- 2009. Ninu ijoba ohun naa lo tun ti sise gege
bi komisanna fun eto ilu ati idagbasoke oro aje.
Lojo
kokanlelogbon osu keje odun 2018 yii ni Fatah Ahmed atawon omo ile igbimo
asofin ipinle Kwara bii metalelogun ya kuro ninu egbe oselu APC ti won si lo
darapo mo PDP, iyen egbe to koko gbe e wole sipo gomina lodun 2011.
Ohun
to mu Fatah Ahmed kuro ninu egbe oselu APC ko seyin bi eni to je alatileyin e
ninu oselu nipinle Kwara, Dokita Bukola Saraki naa se fi egbe APC sile lo darapo
mo egbe PDP ti won ti je omo egbe nigba kan ri.
EYI NI FIDIO AWON ALATILEYIN E… BI WON SE N YO
TI WON N JO…
0 Comments