Loni-in, ojo Aje Monde, ni deede aago mejo abo aaro ni
won ti gbe gomina tele nipinle Ekiti, Ogbeni Peter Ayodele Fayose de kootu l'Ekoo, esun mokanla ni won ka si i lese, bee ladajo tun ti pase pe ki won da a pada si ahamo.
Lara esun mokanla otooto ti won ka si okunrin oloselu
yii lese ni owo bitibiti ti won so pe o gba lowo alakooso eto aabo
lorile-ede yii nigba kan, Aliyu Gusau lasiko to fe dije dupo gomina l’Ekiti.
Lojuese ti
won ti ka awon esun ohun si i lese ni gomina tele yii ti so ni kootu wi pe oun
ko jebi okankan ninu gbogbo esun buruku ti won ka si oun lorun.
Nibe gan-an ni agbejoro to n soju ijoba, Rotimi
Oyedepo ti ro ile-ejo ko tete pase ki won lo fi gomina tele naa
pamo sogba ewon, titi digba ti ile-ejo yoo fowo si i boya ki won gba oniduro e
tabi rara.
Sugbon agbejoro to n soju fun Fayose, Kalu
Agabi, (okan lara onimo nla ninu ise ofin) ko je ki oro ohun bale, ti oun naa
fi bebe wi pe ki won siju aanu wo Ogbeni Fayose, ki won je ko si maa lo sodo
ajo EFCC na, niwon igba ti eto ti n lo lori bi won yoo se gba oniduro e.
Ni bayii, Adajo agba, Mojisola Olatoregun ti
so pe ki won lo fi Fayose si ipamo naa, lodo ajo EFCC, nigba ti igbejo e yoo maa
te siwaju lotunla Wesde Ojoru ose yii.
0 Comments