Awon ebi gbajumo osere alawada nni, Oloogbe
Moses Olaiya Adejumo, eni tawon eeyan tun mo si Baba Sala ti kede wi pe ninu
osu kejila odun yii lawon yoo seto isinku e.
Okan lara awon omo oloogbe ohun, Ogbeni Emmanuel
Adejumo, eni ti awon eeyan tun mo si Boisala lo soro ohun loruko molebi. O ni,
ojo meji ni eto isinku ohun yoo fi waye laarin ojo kefa si keje ninu osu kejila
odun yii.
Te o ba gbagbe; lojo keje osu kewaa odun yii
ni Baba Sala jade laye leni odun mejilelogorin (82) nile e niluu Ilesa, ipinle
Osun.
Gbajumo nla lokunrin alawada yii; kaakiri
agbaye ni won si ti mo on, eyi to mu ijoba orile-ede yii paapaa fun un lami eye
MON, iyen Member of the Order of the Niger (MON).
Bi eto ohun ba se n te siwaju si i, a o maa
fi to yin leti.
0 Comments