GBAJUMO

ATIKU NIKAN LO YE NIPO AARE ORILE-EDE NIGERIA LASIKO YII- GBENGA DANIEL


Otunba Gbenga Daniel, gomina ipinle Ogun tele ti sapejuwe Alhaji Atiku Abubakar, oludije fun ipo Aare labe asia egbe oselu PDP, gege bi eni to kunju osunwon julo.
Lasiko to n ba ileese Channels Telifisan soro lori okan awon eto nipa oro oselu tileese ohun maa n gbe jade losoose lo fidi oro ohun mule.
Ninu oro e lo ti so pe, “Ti a ba n so nipa ojulowo oloselu, ti aaye gba ni gbogbo Nigeria yii, Alhaji Atiku Abubakar ni. Bi won ti se fe e laarin awon Yoruba, bee lenu e tole daadaa laarin awon Ibo, ti ko si see fowo ro seyin ta a ba n so nipa ojulowo omo Hausa.
“Fun idi eyi, irufe eeyan bee lo ye ni Aare orile-ede yii niru asiko ta a wa yii. Eni ti yoo fi ife so gbogbo orile-ede yii papo, ti yoo tun lo imo nla to ni ta a ba n so nipa okoowo sise, lati mu oro aje wa ru gogo si i.”
Gbenga Daniel, eni ti se gomina ipinle Ogun nigba kan ri ni oludari agba fun ajo to n se iponlogo ibo fun Alhaji Atiku Abubabar.     

Post a Comment

0 Comments