Ninu ibanuje okan ni gbajumo
osere tiata Yoruba nni, Ibrahim Chatta wa bayii, mama to bi i ni iku mu lo lairotele.
Lana-an ojo kin-in-ni osu kokanla yii lokunrin naa gba ori Instagram
lo, foto mama e to gun rege lo gbe sori ikanni ohun, nibe naa lo si ti ko o pe ‘Nje
omi ko tan leyin eja bayiii, o digba kan na, maami.”
Ohun ti Ibrahim ko ree pelu foto mama e, bi awon eeyan si ti
ri i ni won ti n ki i, ti won n ranse ibanikedun si i wi pe o ku atemora, o ku
aseyinde mama e.
Akoroyin magasinni yii naa pe foonu e, ohun ti okan lara
awon omo to maa n ba a gbe foonu e dani so fun wa ni pe, o wa lori itage to n
sise lowo, ati pe yoo pe pada to ba setan.
Okan lara awon osere tiata Yoruba to n se daadaa ni Ibrahim
Chatta je, bo tile je pe okunrin yii ki i se Yoruba, sibe, omo Tapa to gbo
gbogbo tifun-tedo Yoruba ni, to si kunju osunwon nibi ka se sinima.
Awa naa ba Ibrahim Chatta kedun iku iya re, bakan naa la fi
n da eyin ololufe wa loju wi pe, a o kan si yin ni kete ta a ba ti gbo gbogbo
bi eto isinku iya naa yoo se lo.



0 Comments