Oloye Olusegun Obasanjo ti sapejuwe bi awon gomina se n gba
owo to ye ko wa lapo ijoba ibile fun idagbasoke ise ilu gege bi iwa jibiti, ti
ko si le mu oriire kankan ba wa lorile-ede yii.
Lasiko ti ajo kan ti ki i se ti ijoba, ti oruko won n je Friends of Democracy, FoD sabewo si baba Iyabo niluu
Abeokuta lo soro yii. Aare lorile-ede yii tele ti so pe, “Iwa jibiti gbaa lawon
gomina kan n hu lorile-ede yii, bi won se n ba ijoba ibile lo apo owo kan naa,
sugbon ti ida mewaa ti won seleri wi pe awon naa yoo maa fi kun owo to ye fun
ijoba ibile, sugbon ti won ki i fi tiwon kun un rara.
“Iru ipo ominira ti ijoba apapo fun ijoba ipinle, iru anfaani
yii gan-an lo ye ki ijoba ibile ni, ki ise idagbasoke to peye le maa waye nibe,
ki awon eeyan to wa nigberiko, kaakiri awon ijoba ibile le janfaani ijoba.” Obasanjo
so pe o seni laanu wi pe, abadofin to le mu awon ijoba ibile wa nipo ominira,
ipinle mesan-an pere lo fowo si i, tawon yooku taku wonle, wi pe ko ni i see
se. O ti sapejuwe igbese ohun gege bi iwa odaran, ti ko le mu ilosiwaju kankan ba
orile-ede wa, ati pe iya nla ni won fi n je awon to wa nijoba ibile.
“Opo ijoba ibile ni ko rowo fi se nnkankan. Won
ko ri owo osu san fawon osise, bee nise gidi kan bayii, ko waye lawon ijoba
ibile. Bee erongba wa lodun 1976, nigba ta a
sagbekale eto ijoba ibile, lajori igbese ohun ni pe ko da duro, ko si je eka
ijoba to maa sunmo araalu daadaa, ki i se idakuda ti won ti so ijoba ibile da
bayii.”
O
tesiwaju ninu oro e pe, ole ni won n fi apo ikowosi alajonni, iyen joint account
se fawon ijoba ibile, ati pe nitori e gan-an ni won
se n tako igbese lati so awon ijoba ibile di ominira ara won.
Ni bayii, ipinle merinlelogun lo gbodo fowo si
i, eyi ti yoo so aba ohun dofin, ti awon ijoba ibile yoo di ominira ara won, ti
won yoo kuro labe akoso ijoba ipinle, paapaa lori oro owo nina atawon ise
idagbasoke ilu.
Awon
ipinle mesan-an ti won ti fowo si i niwonyi; Ogun Bayelsa; Cross River; Sokoto;
Kwara, Niger, Plateau ati Benue.Baba Iyabo ti wa gbosuba nla fawon ipinle
ti won ti gbe igbese gidi yii, bee lo ke si awon merinlelogun yooku lati se
bee, ki ilosiwaju gidi le maa waye lawon ijoba ibile.
O ni, “Ti a ba ri ijoba ipinle kan
tabi awon asofin ti won ba ko lati fowo si igbese yii, eni ibi ti ko feran idagbasoke
ilu niru won.
0 Comments