GBAJUMO

BABA FI IBASUN BA OMO E LAYE JE L’EKOO *WON NI OMO ODUN MEJI PERE NI

Lowo olopaa ni okunrin kan ti won pe oruko e ni Peter Adida wa bayii, nibi to ti n salaye ohun to mo nipa bo se fipa ba omo e, omo odun meji sun, titi to fi fun un ni aisan buruku.
Adugbo kan ti won n pe ni Westwood Estate ni nomba 9, Oyetayo Olafisoye ni Badore, niluu Ajah ni won so pe okunrin naa n gbe. Satide, ojo Abameta to koja yii lowo awon olopaa ti te e, ti won si ti mu un si tesan won niluu Langbasa lagbegbe naa.
Ninu oro oga agba ni tesan olopaa ohun, Arabinrin Ada Okafor (SP) lo ti so pe, “Iwadii wa fi han wi pe nise ni okunrin yii ba omo e, omo odun meji sun titi to fi ko aisan buruku ran an.
Ninu oro alukoro fun ileese olopaa, Chike Oti, (CSP) ni tie lo ti so pe “Nigba ti okan lara awon olopaa ti won je obinrin beere lowo omo naa wi pe ta lo ba se iru ere buruku bee, nise lo nawo si baba e, to si tun juwe orisirisi ara mi-in ti okunrin naa fi da lasiko to n fipa ba a lopo.”

O ni komisanna olopaa, Imohimi Edgal ti pase wi pe ki won gbe igbese iwadii gidi lori oro ohun, bakan naa lo ti wa ro awon obi ati alagbato lati maa mojuto awon omo won daadaa, nitori pe pupo ninu awon irufe onise ibi ohun ni won gba igboro kan bayii.

Post a Comment

0 Comments