GBAJUMO

ASIRI OHUN TO KOBA IJOBA SARAKI NI KWARA REE *ATAWON TI WON TU U LASIIRI FAWON BOLA TINUBU

Dokita Bukola Saraki, aare ile igbimo asofin agba

APA KETA
Sa o, odun 2019 yii gan ni nnkan yi biri, o si jo pe wahala to bere ninu molebi awon Saraki lodun 2011, ninu eyi ti Bukola Saraki ti fidi baba e, Olusola Saraki janle ninu ibo to waye lodun naa lohun-un, odun yii gan-an ni igba yanga e fo patapata.   
Lodun 2018 gan-an ni wahala ohun bere, Saraki binu kuro ninu egbe oselu APC to n sejoba loke, bee lawon nnkan mi-in tun waye, nigba ti ibo yoo si waye lodun 2019, nise loro daru patapata o, akoso Kwara to ti wa lowo awon Saraki lati odun 1978 si 79 wo pale patapata leyin ogoji odun.
ASIRI OHUN TO KOBA IJOBA SARAKI NI KWARA REE
Salari , iyen owo osu awon osise pelu ohun akoko to sakoba fun un. Won ni bi won se je awon oluko lowo osu, bee loro ohun kan awon osise kansu atawon ti won ti feyin ti lenu ise. Gbogbo awon eeyan wonyi ni inu won ko dun, bee ni won reke ijoba awon Saraki daadaa digba ibo, ki won le fibo da seria nla fun won.
Opolopo igba ni awon osise se iwode ti won fehonu han, paapaa lori bi awon eeyan se n binu pokunso nipinle naa, nigba ti won ko ri owo osu gba deede. Bo tile je pe ki i se Bukola Saraki lo wa nipo gomina, sibe igbagbo awon eeyan ipinle ohun ni pe, Fatai Ahmed ti se gomina ko le da ohunkohun se lai je pe Bukola Saraki fun un lase e. Bee ni inu n bi awon eeyan gidigidi, ti won si n leri omo Baba Oloye sinu wi pe awon yoo gbesan t’ojo ba ya.
Bola Tinubu, asaaju oloselu APC
Ohun mi-in ti won lo tun sakoba fun un ni idigunjale to sele niluu Ofa, nibi tawon kan ti n naka si Bukola Saraki wi pe oun gan an lo n lo awon janduku ohun fun toogi oselu. Won ni lara irinse ti won fi n se toogi oselu naa ni won lo lojo ti won digun ja awon banki lole niluu Ofa, nibi ti opo emi ti bo, ti awon olopaa paapaa padanu awon eeyan won repete ninu osu kerin odun 2018.
Ninu osu keje odun 2018 ni Saraki atawon eeyan e ninu egbe oselu APC ya kuro ninu egbe naa lo darapo mo PDP, bee ni gomina ipinle naa, Abdul-Fatah Ahmed naa ba a lo atawon omo ile igbimo asofin ni Kwara.
Igbese yii lo so o deni to wa ninu egbe oselu alatako, bee ni agbara ijoba apapo ko si fun un mo, nigba ti eto idibo si waye, nibe gan-an ni idaamu ti sele, bo se di pe Saraki pelu egbe PDP e ni Kwara fidi remi niyen o, ti APC si ko gbogbo ipo lo patapata.
Ohun mi-in to tun mu un kuna ni bi pupo ninu awon alatileyin e se ba egbe oselu APC lo, awon eeyan bii Ibrahim Olori-egbe; Yinka Aluko, Moshood Mustapha, Cook Olododo, Yahaya Seriki, Abdul-Yekeen Alajagusi atawon mi-in. Wamu bayii ni won duro  ti egbe oselu APC, bee ni aburo e paapaa, iyen Alhaja Rukayat Gbemisola Saraki naa pelu awon alatako Booda e yii, bee ni won ri i pe won gba Kwara lowo Bukola Saraki, ti egbe oselu APC si diyawo tuntun ni Kwara.
Fatai Ahmed, Gomina
Kwara to n lo
Oro esin naa tun pelu ohun ti won fi koba a ni Kwara, paapaa niluu Ilorin ti won ko mu esin Musulumi ni kekere. Won ni Bukola Saraki ki i se Musulumi. ati pe Gideon loruko to n je laarin awon Kristeni. Eleyii naa pelu ohun ti won fi n polongo ibo tako o.
Bee gege ni egbe osleu APC tun n pariwo fawon Kristeni naa wi pe, asiko niyi fawon naa lati se ‘O to ge’ fun ijoba Saraaki ni Kwara.
Yato si eyi, awon eeyan Kwara ti won wa ni apa Arewa (Kwara North) naa n pariwo wi pe won n yan awon je gidigidi, toro ba doro oselu ni Kwara, bee ni egbe oselu APC fiyen wole si won lara, ti won si so pe tawon yen naa ba setan lati se ‘O TO GE’ fun Saraki, ko si ohun ti won n fe ninu oselu ti ko ni i to won lowo.
Ohun mi-in to tun koba a ni idasile awon ileese redio aladaani ni Kwara, nibi tawon eeyan ti n gbo orisirisi iroyin, paapaa eyi to n tu asiri ijoba ati irufe imunisin ti awon Saraki ko awon eeyan ipinle naa si. Awon eto olokan-o-jokan to n jade lati ileese Radio Sobi FM, paapaa eto kan ti won maa maa n se itupale awon koko inu iwe iroyin ninu e, eyi ti won pe ni Feli-feli, logan ni eto yii di ayanfe araalu, nitori awon iroyin ti ileese redio ijoba ko le gbe jade lawon n gbe ni tiwon. Bee lo fun awon eeyan lanfaani lati mo gbogbo ohun to n sele pata ti iro si se bee salo, n ni ooto nipa ijoba ba se bee gbode kan ni Kwara.
Abdul-Rasaq,
Gomina Kwara tuntun
Ariwo O TO GE tawon omo egbe APC naa gbe wo Kwara ko sai ni ipa nla to n ko o, kaakiri ipinle ohun ni won ti n wi i. Koda titi de awon ipinle mi-in nile Yoruba ni won ti n gburoo ariwo O TO GE yii, tawon naa si n ba won wi i, eyi to fihan wi pe awon omo Yoruba nipinle mi-in paapaa n fe ki awon omo Kwara bo lowo Saraki.
 Ohun mi-in to tun sakoba fun un ni orisirisi esun ikowoje ati sise owo ilu basubasu. Bi won ti n fesun kan Saraki wi pe oun lo wa nidii owo nla nla bee ni inu awon eeyan Kwara n baje, paapaa awon osise ti won n je lowo osu ni inu won ko dun nigba ti won n gbo ariwo bilionu-bilionu naira ti won so pe Saraki ji ko, ti awon ko si ri owo osu gba debi pe won yoo rowo fi jeun.
Ohun to tun mu oro daru patapata ni bi asiri se tu wi pe Dokita Bukola Saraki si n gba owo osu lowo ijoba Kwara gege bi gomina, bee lo tun n gba ajemonu owo ifeyinti gege bi eni to ti se gomina ri, bo tile je pe owo osu ati ajemonu lorisirisi naa si n lo gege bi aare ile igbimo asofin.
Bi asiri yii se tu sita, bee lawon ileese radilo aladaani ti won wa ni Kwara n gbe e, lasiko ti won ba n se itupale e lori koko inu iwe iroyin ni gbogbo igba. Bi won se n pariwo e yii, bee lawon eeyan Kwara n gbo, ti iye won si n si; wi pe ni tododo, nise ni okunrin naa n yan awon je gidigidi.
Bi ogun yen se bere were niyen ni Kwara o, ki oloju si too se e, ibo Aare ati ile igbimo asofin wole, sugbon dipo ki Bukola Saraki jawe olubori, nise lo fidi remi, bee ki i se oun nikan o, gbogbo awon to dije loruko egbe oselu PDP ni idaamu ohun ba, ti egbe oselu APC si gba Kwara mo won lowo patapata.
Bee gege loro tun ri nigba ti ibo gomina atawon ile igbimo asofin naa wole de, egbe oselu APC wole ni Kwara, n ni PDP ba di atemere patapata.    
Lara awon adigunjale to fo banki l'Ofa ree
nigba ti won n sise ibi won lowo
Te o ba gbagbe, lasiko igba ti eto idibo kansu waye ni Kwara, kanselo mejo lo wole, ti alaga ijoba ibile kan naa si wole so o, ti won ki i se omo egbe oselu Buklola Saraki. Eyi to tubo ko idaamu ba awon Saraki ni bi omo egbe oselu APC se jawe olubori lasiko ti eto idibo waye lati ropo omo ile-igbimo asoju-sofin to jade laye, eni to n soju agbegbe Ekiti/Irepodun/Isin.
Latigba naa ni okan awon Saraki ko ti bale mo, ti won si n wa gbogbo ona ti awon ota ko fi ni i yo won, paapaa bo ti se je pe ninu egbe alatako ni won wa bayii. Bee lawon Lai Muhammed, Bola Tinubu naa si n tenumo wi pe, gbogbo ohun to ba gba lawon maa fun un, nise lawon yoo gba ipo oselu Kwara kuro lowo Bukola.
Lai Muhammed, minisita to wa nipo
asaaju oloselu egbe APC ni Kwara
lasiko yii niyen
Ki omi ma ba a teyin wo igbin lenu, won ni eyi gan-an lo mu Dokita Bukola Saraki gba tikeeti ipo asofin agba lowo Gomina Abdul-Fatah Ahmed, to si da a pada fun eni to wa lori ipo ohun lowo, iyen Seneto Abdul-Rafiu Ibrahim.
Bo tile je pe won gba tikeeti yii fun eni to wa lori ipo ohun lati tun lo leekan si i, nibe gan-an ni idaru-dapo ti waye, nitori nise ni ajo INEC fariga wi pe Gomina Fatah Ahmed lawon mo gege bi oludije, ati pe oruko e gan-an lo wa ninu iwe awon.
Saaju asiko yii, pupo ninu awon igbese kan ni won so pe o ti waye, eyi to mu Seneto Bukola Saraki maa kuna diedie, sugbon ti okunrin oloselu Kwara yii ko tete fura...


E MAA BA WA KA LO...

Post a Comment

0 Comments