Loni-in
ni won yoo tun gbe Seun Egbegbe, Olajide Kazeem lo sile ejo lori esun jibiti
ati gbajue ti won fi kan an.
Ni
bayii, o ti le ni ogun osu ti okunrin gbajumo omo jayejaye Eko, to tun maa n
gbe awon olorin laruge , to si tun maa n gbe sinima jade ti wa lahamo awon
olopaa bayii.
Esun
ti won fi kan an ni pe, o lu awon Hausa kan ti won maa n se owo ile okeere si naira
ni jibiti owo repete. Won laarin odun 2015 si 2017 ni Seun Egbegbe fi n hu iwa
odaran ohun.
Bo
tile je pe ile-ejo ti fun okunrin omo jayejaye yii lanfaani lati maa ti ile wa
jejo, sibe awon ohun to ye ko se, ti beeli re yoo fi bo si i, Seun Egbegbe ko ti
i ri i ko kale.
Saaju
asiko yii ni Onidajo Oguntoyinbo ti ile ejo giga kan l’Ekoo ti ni ki Egbegbe ati
enikeji e, ti won jo mu, Oyekan Ayomide, lo wa owo beeli milionu marun-un naira
eni kookan wa, bee ni won tun gbodo ni oniduro, eni to je oga agba onipo
kerindinlogun (level 16) ninu ise ijoba, ti tohun yoo tun ni ile nla l’Ekoo, to
si setan lati ko gbogbo e sile, gege bi iduro fun Seun ati ikeji e.
Ojo
kewaa osu keji odun 2017 lo ti wa ni ahamo. Ohun ti ileese olopaa so nile-ejo ni
pe, o le ni ogoji ileese ti won ti maa n se owo ile okeere, ti Seun Egbegbe fi
ogbon jibiti gba owo lowo won laarin odun 2015 si odun 2017. Awon owo ti won so
pe Egbegbe fi ogbon jibi gba ree lowo awon Hausa; owo naira to fe to ogoji milionu
naira (N39,098,100), bakan naa ni won lo tun gba awon owo ile okeere yii; egberun
lona aadorun-un dola ($90,000) ati egberun mejla abo owo poun ile Geesi.
Esun
ti won ka si Seun ati enikeji e lese fe to ogoji, bee lawon mejeeji ti so pe awon
ko jebi esun ohun.
Sa
o, o le ni ogoji Hausa ti won n se dola ti won so pe awon setan lati jerii tako
Seun Egbegbe ati ikeji e nile ejo.
Ojo
kewaa osu keta ti igbejo ohun waye , o le ni ogbon eeyan ti won wa jerii tako o,
sugbon eto igbejo ohun ko fi bee lo daadaa, nitori pupo ninu awon elerii yii ni
won ko le so ede geesi, eyi to mu ile-ejo lo wa ogbufo fun won.
Loni-in
ni igbejo mi-in yoo tun waye, gbogbo bo ba se lo, le o maa gbo.
0 Comments