Gbajumo olorin esin Islam nni, Alaaji Ahmad Alawiye ti
sapejuwe Sheik Abdullahi Solademi Olodo, gege bi ojulowo Muslim ti igbe aye won
dara pupo, ti o si tun je awokose gidi fun gbogbo Muslumi.
Laipe yii ni won kede iku Afaa yii, eni ti se okan lara awon
Alfa nla ninu esin Islam, to tun je ojulowo Sheik nilana Torika Tijaniya.
Ilu Ibadan ni adugbo Odinjo, Ni Masfala ni won so pe Sheik
yii kole si.
Omoleyin Sheik Tijani gidi ni won pe e paapaa.
Ohun ta a gbo ni pe ninu osu yii gan-an ni baba naa fe lo si
orile-ede Senegal ni Kaola, niluu awon Sheik Ibrahim Niyyass lohun-un.
Ninu oro Ahmad Alawiye lo ti so pe ko si maolud nabbiy ti
won maa se nile Yoruba atawon ibomi-in kaakiri laarin awon ijo Tijanniya ti won
ko ni i pe Sheik Olodo.
O ni, “Gbajumo nla ni laarin awon Sufi, bee lo je eeyan pataki
to maa n so ododo. Alfa nla kan ni to tako gbogbo ohun to le maa tabuku ba
ojuna Sheik Ahmad Tijani, bii ki eeyan maa ko tesuba sorun abi awon iwa ikorira
bii ki eeyan maa muti tabi se sina lojuna ohun.
“Bi omode se fe won, bee lawon agbaagba naa fe e pelu, imo
kikun lo ni, bee ni ki i rori lasan soro.”
Alawiye te siwaju ninu oro e pe, “Lojo ti won jade laye, ilu
Ikorodu ni won ti lo seto; eto pataki meji ni won ni laduugbo yen lojo naa, bi
won se n pada lo si Ibadan, eemeji otooto ni moto ti won seto e fun won yonu
lojuna. Nigba ti won yoo si fi gbe moto ti won pade won, bi won se n wo Ibadan
lookan, ti awon omo keu won ti sare wa pade won, ki won gbe won sinu e bayii,
nibe gan-an ni olojo ti de.
“Baba daadaa ni; nigba aye won, koda o loruko ti won maa n
pe mi, won a ni, Afaa omo Afaa, tabi ki won pe mi ni Wolii omo Wolii.
“Mo ti n sere fun won bo lasiko maolud won lati nnkan bii
odun mejidinlogun seyin ni.
Lodun yii gan-an ni
won sese seyawo tuntun, ki Olorun ba wa te won safefe rere.”
0 Comments