Laipe ni Iyalode Ojodu Berger, Oloye Yetunde Babajide, eni
ti se Aare ileese YEFADOT Group of Companies se ifilole awon oloye egbe e niluu
Igbogbo n’Ikorodu pelu erongba lati satileyin fun ipada-sipo Aare Muhammed
Buhari ati Babajide Sanwo-olu, oludije fun ipo gomina l’Ekoo.
Ninu oro e lo ti so fawon eeyan Igbogbo, Ikorodu ati agbegbe
e wi pe, o se pataki ki awon eeyan jade lati kede fawon ara won yooku wi pe
ijoba Aare Muhammed Buhari nikan ni Nigeria nilo lasiko yii, ati pe asise nla
ni yoo je ti won ba seesi dibo fun egbe oselu PDP nitori ko si anfaani kan
bayii ti egbe naa ni fun Nigeria mo.
Yato si awon eya Yoruba ti won peju pese sibe lojo naa, bee
gege ni Kabiesi awon eya Igala naa wa nikale, ohun to si so lojo naa ni pe gbogbo
eya Igala pata ni yoo dibo won fun Aare Muhammed Buhari ati Babajide Sanwo-olu,
eni ti se oludije fun ipo gomina l‘Ekoo.
Bakan naa lawon eeyan
Nupe atawon mi-in naa ko sai ba won peju pese sibe. Ohun kan ti Oloye
Yetunde fidi e mule fawon eeyan yii ni wi pe ki kalulu gbiyanju lati ni ise kan
pato lowo, paapaa ise agbe, nitori anfaani to wa ninu e ko kere.
O te siwaju ninu oro e pe, “Lati le mu un rorun fun araalu, iyen
gan-an lo mu ileese wa da ileewe agbe sile, eyi ti a pe ni YEFADOT Agric
School. Ohun kan ti a n ko nibe ni bi eeyan se le di agbe, ti yoo si tun lanfaani
lati gba eto eyawo, bee gege ni saare ile repete wa fawon eeyan leyin ti won ba
ti yege ikekoo won, ti a o si tun ko won lo si Ibadan, nibi ti won yoo tun ti
ni iriri nla si i.”
Iyalode Ojodu, eni to tun je asaaju awon obinrin nile Yoruba
loruko egbe to n polongo ibo fun Aare Muhammed Buhari ti so pe, ti awon eeyan
orile-ede yii ba le fibo won gbe Buhari wole leekan si i, oriire nla ni yoo de
ba gbogbo omo Nigeria, nitori pe ko tun si egbe oloselu kankan to le se e
lasiko yii. Bakan naa lo ro awon eeyan Eko lati jade dibo won lojo ibo fun
Babajide Sanwo-Olu.
E WO FIDIO OLOYE YETUNDE BABAJIDE...nibi to ti salaye eto nla ti Buhari tun ni fun araalu
0 Comments