Bo tile je pe eni odun metalelogorin (83) ni Dokita
Frederick Fasehun, oludasile egbe ajijangbara ile Yoruba nni, iyen OPC lo laye,
sibe agbosogbanu lopo awon omo Yoruba kaakiri agbaye si ka iku baba naa si.
Ninu atejade ti Aare Ona Kakanfo ile Yoruba fi sita, Iba
Gani Adams lo ti sapejuwe iku olori awon OPC yii gege bi adanu nla fun iran
Yoruba.
Bee gege ni egbe AFENIFERE naa ti so pe, kayeefi ni, ati pe
iku to pa baba naa lasiko yii, ijanba nla lo se fun awon Yoruba ati Nigeria
lapapo.
Gani Adams ninu oro e fawon molebi oloogbe yii lo ti so pe, “Agbosogbanu
gbaa loro ohun je lasiko ti mo gbo iku baba wa, eni ti se oludasile egbe OPC
loni-in ojo kin-in-ni osu kejila odun 2018. Ni tododo, akoko idaro gidi ni asiko
yii je fun gbogbo omo egbe OPC, awa omo Yoruba, orile-ede Nigeria ati gbogbo
agbanla aye. Mo fe fi asiko yii ki gbogbo ebi ku atemora, bee gege ni inu wa
dun lori ipa manigbagbe ti Olori wa yii ko nipa idagbasoke awujo nigba aye e,
paapaa gege bi onimo isegun oyinbo ati oloselu pelu asiwaju nla ti a ba n so
nipa eni to fe ohun rere fun awujo e.”
Iba Gani Adams ninu oro e fi kun un wi pe, eeyan nla kan ni
Oloogbe Fasehun ti oun gba ara e koja, ti oun si jere gidi gege bi omoluabi
eniyan ni gbogbo akoko ti awon jo fi wa ninu irepo nla.
O ni, “Odun marun-un gbako ni mo lo lodo Oloogbe Fasehun,
bee ti a ba n so nipa eni owo, ti gbogbo ola pata ye, Baba Frederick Fasehun
ni.”
O sapejuwe ajosepo oun ati Oloogbe naa gege bi ajosepo asiwaju
gidi; ti a tun le pe ni ajosepo baba si omo. Bakan naa lo so pe oloooto eeyan
ni, ati pe loruko oun atawon molebi oun pelu gbogbo awon omo egbe OPC lapapo,
awon ba awon ebi Oloogbe ohun kedun iku to pa baba naa, bee lo toro ki Olorun ba
won mu ile won duro. Siwaju si i, o ti so pe, ko si iru eyin ati aponle ti won
le se fun baba naa, ti Frederick Fasehun ko to bee, koda o tun ju u lo paapaa.
Ninu oro awon omo egbe Afenifere ni tiwon ni won ti sapejuwe
baba naa gege bi ogunna gbongbo to ja fitafita lori oro ibo June 12, bakan naa
ni won so pe adanu nla ni iku oludasile egbe OPC yii je fun orile-ede yii,
paapaa niru asiko ta a wa yii. Won ti wa ro awon ebi e wi pe ki Olorun tu won
ninu.
Eni odun metalelogorin
(83) ni Dokita Frederick Fasehun ki olojo too mu un lo loni-in, ojogbon onimo
isegun oyinbo ni, oun naa lo seto bi egbe oselu Unity Party of Nigeria se tun pada
saye leyin ti egbe naa ko si mo fun opo odun. Egbe oselu Oloogbe Obafemi
Awolowo ni, o si ti wa tele ri lawon odun 1970, to se daadaa pelu.
Awon ileewe bi Blackburn College ati
Aberdeen University College of Medicine lo ti kekoo niluu oyinbo. Bakan naa lo
tun te siwaju lawon ileewe wonyi; Liverpool Postgraduate School nibi to ti
gboye Fellowship at the Royal College of Surgeons.
Lodun 1976, lo te siwaju lo si orile-ede China pelu iranlowo ajo World Health
Organization ati United Nations Development Scholarship Program lati lo kekoo
si i nipa imo isegun.
Nigba to di 1977, lo ba won da eto
ise isegun kan kale ti won n pe ni Acupuncture, (imo isegun ti won maa n lo
abere lati fi gun eeyan lawon orikerike ara fun itoju to peye) ni Lagos
University Teaching Hospital. Odun 1978 lo kowe fipo sile to si da osibitu tie
naa sile, eyi to pe ni Besthope Hospital and Acupuncture Centre l’Ekoo. Lawon
asiko kan, ile itoju alaisan yii lawon eeyan gba wi pe eeyan ti le gba itoju to
peye ju ti a ba n so nipa itoju eniyan pelu ilana lilo abere lati fi gun eeyan lawon
orikerike kan ninu ara, ti iwosan yoo si de, eyi tawon Chinese maa n lo daadaa.
Osu mokandinlogun (19) loun naa fi
sewon Abacha nitori oro June 12, bee ti won ba n so nipa ojulowo omo Yoruba,
eeyan nla ni Fasehun n se.
0 Comments