Se ohun ti Wolii ijo Mountain of
Blessings and Miracle Church so nigba naa ni pe, ti Funke Akindele ba fe loko,
to si tun fe di olomo laye, nise ni ki o gbadura gidigidi, ki o si sunmo Olorun
daadaa. Wolii yii tun fi kun oro e wi pe, eni ti ko loruko, ti ko lokiki nla
bii Funke ni ko tete wa fi se ade ori, ki oun naa le ba ni ibujokoo ayo.
Ohun ti Faleyimo so nigba naa
ree, bee lo tun so nipa awon iran mi-in ti Olorun fi han an, paapaa nipa awon
osere tiata, awon olorin, oloselu atawon oniroyin.
Ni kete ti iroyin gbalu wi pe
Funke ti di iya ibeji loke okun, n lawon eeyan ti bere si pe baba yii ni wolii
eke. Bi awon iwe iroyin kan se n gbe e, bee ni won n pin in kaakiri ero
ayelujara, tawon eeyan n se yegede Wolii araye-rorun.
Sa o, Faleyinmu ti so pe, asiko ti oun yoo soro ko ti i to. Ninu alaye to se fun Magasinni yii lo ti so pe, “Inu
mi dun ti Olorun ti ba Funke Akindele se e, ti oun naa ti dolomo laye. Nipa
awon eeyan ti won n bu mi, emi ko ni ohunkohun ti mo fe so bayii, emi ko ni mo soro,
Olorun lo wi, bee lo so nigba naa wi pe, ki Funke gbadura gidigidi ki o le ri ona
abayo.
“Awon to n soro ki won maa so
lo, ti asiko ba to, Olorun alaaye yoo tun gbenu mi soro.”
Ohun to so fun wa niyen. Se
saaju asiko yii, okan lara awon araye-rorun ni Wolii Olagoroye Faleyinmu n se,
o pe ti okunrin omo ipinle Ondo yii ti maa n so pe, to ba je ojo kansoso pere
ni, Olorun ti so pe Buhari yoo sejoba ni Nigeria.
Yato si eyi, Wolii yii naa lo
so pe, ki Deji Akure ti won yo nipo nigba kan se pelepele wi pe oun ri ewu
niwaju e. Nibere odun lo soro ohun lodun naa lohun-un, nigba ti yoo si fi di
inu osu kerin, oro lo se bii oro laarin Deji Akure, Kabiesi oba alaye laarin
oun ati iyawo e, nni baba ba ko patie bo olori nita gbangba. Waranwere loro ba
di bami-in mo oba alaye lowo.
Siwaju si i, Wolii yii naa lo so pe eto idibo ko ni i waye
ni Nigeria lodun 2011. Te o ba gbagbe, odun yen-an gan-an ni won sun ibo siwaju.
0 Comments