Lara awon to farapa nibi isele ohun ni Alhaji
Musiliu Akinsanya, eni tawon eeyan tun mo si MC OLU OMO. Obe ni won so pe won
fi gun un nikun, bee ni won gun un lowo ati ori paapaa. Osibitu kan tri won n
pe ni EKO Hospital ni won so pe won sare gbe okunrin onimoto yii lo, nibi ti
won ti n toju e bayii.
Elomi-in toun naa ba isele ohun rin ni okunrin
onimoto kan ti won pe oruko e ni Afeez Ismail, won ni, seni won yin in nibon, bo
tile je won sare du emi e, sibe, osibitu LASUTH lo pada ku si.
Yato si eyi, awon oniroyin meta lawon naa fara
gba ninu isele ohun; Emmanuel Oladesu, Temitope Ogunbanke ati Abiodun Yusuf,
ibon ni won so pe o ba won, ti won si n gba itoju bayii losibitu.
Sa o, ileese olopaa ti kede wi
pe oun n wa okan lara awon oga onimoto l’Ekoo, Mustapha Adekunle, eni tawon
eeyan tun mo si Sego. Won ni, okunrin naa ni opolopo alaye lati se lori bi
wahala se sele nibi ipolongo ibo to waye loni –in, nibi tawon eeyan kan ti farapa,
ti emi si tun sofo nibe pelu.
0 Comments