Gege bi fonran kan to gba igboro kan lori facebook, ninu eyi
ti gbajumo sorosoro nni, Ogbeni Gbenga Adewusi, eni tawon eeyan tun mo si
Bayowa ati Yomi Fabiyi pelu Baba Suwe wa. Nibe gan an ni won ti fidi e mule wi
pe loooto ni Ojise Olorun yii fun baba Suwe lowo ohun, ati pe okunrin alawada
yii ko ni i pe lo siluu oyinbo nibi ti won yoo ti toju e daadaa.
Gbenga Adewusi gan-an lo se ifirowanilenuwo fun Baba Suwe
ninu fonran ohun alaye to se lo bayii:
“Loooto ni Mama Rev. Esther Ajayi fun Baba Suwe lowo nla
lati fi toju ara e. Okurnin kan ti won n pe ni Paseda gan-an ni Ojise Olorun
yii so pe ko maa wa mi kiri. Won lawon fe ri Bayowa, igbagbo won ni pe ti won
ba ti ri mi, won maa ri Baba Suwe. Iya daadaa yii lo so pe oun fe ki Baba Suwe
tete maa lo si ilu oyinbo ko lo gba itoju to peye, a si dupe lowo Olorun wi pe milionu
mewaa naira (N10,000,000) ni won san sinu akaunti Baba Suwe bayii.”
Nigba ti Bayowa ni ki Baba Suwe naa soro, okunrin alawada
yii so pe, bii ere loun tie koko pe e nigba ti oun ri aago oun to dun, ti oun si
ba milionu mewaa naira leekan naa ninu akaunti oun. Mo dupe o, gbogbo omo Nigeria pata ni won dide si oro mi, adura latodo Kiristeni, awon Musulimi atawon eeyan pata ni won se bebe. Mo dupe o. Mo dupe lowo gbogbo awon ebi mi naa, won ri iranlowo, bee ni won fi toju mi daadaa.”
Alaaji Babatunde Omidina so pe, Olorun gan-an lo yo oun, nitori o pe ti oun ko ba ti dake. O ni lati bi odun meta seyin ni aisan ohun ti le gan-an, sugbon ti Olorun si ba oun se e, ti oun si wa laaye.
Alaaji Babatunde Omidina so pe, Olorun gan-an lo yo oun, nitori o pe ti oun ko ba ti dake. O ni lati bi odun meta seyin ni aisan ohun ti le gan-an, sugbon ti Olorun si ba oun se e, ti oun si wa laaye.
Baba Suwe ti wa dupe lowo Ojise Olorun yii, bee lo dupe lowo
gbogbo omo Nigeria pata lori aduroti won latigba ti oro ohun ti gbode kan.
Te o ba gbagbe, Magasinni Alore yii lo koko ke gbajare oro
ohun sita ni nnkan bi ose meloo seyin pelu akole yii,
WON NI ARA BABA SUWE KO
YA GIDIGIDI O *N LAWON OLOLUFE E BA NI KI AWON TINUBU, FASHOLA ATAWON OLOWO NLA
RAN AN LOWO lojo kesan-an osu keji odun yii.
Latigba naa loro ohun ti gba igboro kan, ti awon eeyan si ti
n wona abayo si ohun to n se e, paapaa latari eto edawo fun un.
Lara ohun ta a gbo ni pe; igbakeji aare orile-ede yii,
Ojogbon Yemi Osibanjo naa fun un Baba Suwe ni milionu kan naira, bee lawon omo
Nigeria lorisirisi ko sai ran an lowo, paapaa awon omo egbe osere tiata won,
iyen TAMPAN.
Ju gbogbo e lo, Baba Suwe ti n dupe o, bee ni ko ni i pe ti
won yoo fi gbe e lo gba itoju loke okun.
0 Comments