Ninu ogba ewon Kirikiri l’Ekoo ni Peter Ayodele,
omo ogun odun wa bayii, nibi to ti n seju pakopako, leyin ti oun ati ore e ji
pata iyale ile kan ka l’Ekoo.
Loni-in ojo Isegun Tusde ni won ko awon mejeeji
wa sile ejo, iyen Peter Ayodele, ati Chibuzor David, toun je omo odun
mokanlelogun. Ise kondokito ni won so pe awon mejeeji jo n se.
Agbegbe kan ti won n pe ni Ejigbo ni won so pe
David n gbe, nigba ti Ayodele ni tie n gbe niluu Osodi l’Ekoo. Koko esun meji
ni won fi kan won nile-ejo majisireeti kan n’Ikeja.
Bi
won ti se ka esun ohun si won leti ni Ayodele ti so pe loooto loun jebi, nigba
ti David ni tie so pe oun ko jebi rara.
Adajo
ile-ejo naa; Arabinrin M.O. Tanimola, ti pase wi pe ki won lo so Ayodele si ogba
ewon Kirikiri na, ti atunyewo esun ti won fi kan an yoo si maa te siwaju; bee
lo ti ni ki David maa ti ile wa jejo leyin ti won gba oniduro e pelu owo
egberun lona egberin naira (N80,000) pelu oniduro meji.
Saaju
asiko yen ni olopaa to wa nidii esun ti won fi kan won, Insp. Aondohemba Koti, so
fun ile ejo wi pe lojo kefa osu keji yii ni owo te won lagbegbe Idi-Oro, nitosi
Mushin, ti awon si ka pata obinrin meta mo won lowo. O ni, obinrin kan ti oruko
e n je Kehinde Oladimeji lo ni awon pata ohun, ati pe oogun buruku ni won fe fi pata
iyawo-oniyawo se.
Olopaa
yii so pe, nise lawon mejeeji fipa wole obinrin naa, ti won si ko o ni pata
nibi to sa a si, lasiko tiyen ti sun lo.
O ni, “Ori
obinrin yen ti ko ni i gbabode lo je ki owo wa te won, nibi ti awon olopaa ti n
yi igboro kiri lowo wa ti te won. Ibeere ta a bi won ni pe, nibo ni won n lo
niru asiko yen, nigba ta a si wo ara won, pata obinrin meta la ba lowo won,
nibe gan-an la ti fura wi pe ejo won lowo ninu.
“Nigba
ta a foro wa won lenu wo ni won jewo wi pe nise lawon wole ji pata ohun nile
obinrin kan, nibe yen lati ni ki won mu wa lo sibe, nigba ti eni to ni pata naa
si ri i, o ni loooto; oun loun ni won.
Won ti so pe iwa odaran patapata ni won hu yii,
ati pe o lodi si ofin Eko, bee lo see se ki won sare lo sewon odun marun gbako.
Won ni ewon odun meta akoko ni wi pe won jale, bee
ni ewon odun meji mi-in tun wa fun won nitori ti won gbimopo lati sise ibi. Won
ni ti won ba fi le jebi peren, ewon odun marun-un marun-un lawon mejeeji yoo jo
sare lo se.
Ni
bayii, won ti sun igbejo mi-in si ojo kerin osu kerin odun yii.
0 Comments