Okunrin oloselu kan wa ni Nigeria nigba kan, laarin odun 1979 si
odun 2012 lo fi migboro titi nidii oselu Nigeria, Abubakar Olusola Saraki
loruko e, omo ilu Ilorin ni, bee omo Iseyin, nipinle Oyo ni iya to bi n se.
Odun 1933 ni won bi baba yii, o si pe laye daadaa, ti enu e si
tole pelu ti a ba n so nipa awon oloselu ni Nigeria, paapaa nipinle Kwara.
Imo ise iwosan oyinbo ni Olusola Saraki ko loke okun, eyi to so
o di dokita alabere. Bee lo fi sise daadaa ko too ya bara
sidii oselu, ise oselu yen gan an lo si so o deeyan nla ni Nigeria, ti won tun
mo on kaakiri agbaye.
Odun 1964 gan-an loruko lokunrin yii koko jade ninu oro oselu
Nigeria, nigba to dije dupo kan lati soju ilu Ilorin, sugbon baba naa fidi
remi, won ko dibo fun un, se ekuluju ni, nigba naa, eyi to tumo si, eni to sese
de, ti ko ti i ni opo gidi kan ninu oselu.
Sugbon nigba to di odun 1978 si 1979 ti oro oselu bere pada ni
Nigeria, Olusola Saraki tun gbiyanju leekan si i, nibe yen gan an ni Olorun ti
saamin si irin-ajo e nidii oselu, bo se bere niyen o, to si di araba nla.
Nigba naa, omo egbe oselu NPN ni Olusola Saraki n se, bee asaju
ni nile igbimo asofin agba nigba yen.
Fun opo odun ti okunrin yii fi se oselu, ko sigba to ko egbe
oselu jade ti ki i jawe olubori, bee lo je pe enikeni ti Saraki ba fowo si wi
pe oun ni yoo di ipo kan mu ninu oselu, eni ti yoo so pe rara, ko see se, ko si
ni gbogbo Kwara lasiko ti a n wi yii.
Bi Dokita Olusola Saraki se di igi araba nla ni Kwara ree,
ti okiki e si kan daadaa kaakiri gbogbo Nigeria. Bee lo tun je pe, laarin odun
1979 si 1983 ti ijoba tiwa-n-tiwa fi wa lorile-ede yii, agba oje ni okunrin yii
n se ninu eto oselu Nigeria.
Ni kete ti oro oselu tun bere pada, paapaa lasiko ijoba
Babangida, Olusola Saraki naa wa lara awon oloselu ti won fe di aare orile-ede
Nigeria, bee ni igbiyanju baba naa te siwaju titi di odun 1999, ti ijoba pada
sowo alagbada patapata.
![]() |
Posita Saraki ree lodun naa lohun-un |
Bo tile je pe Olusola Saraki, oga agba nidii oselu niluu
Ilorin nipinle Kwara ko ri Aare Nigeria je, sibe oloselu nla kan ni ti won bowo
fun daadaa, bee ni ko seni kan bayii to je so pe bawo ni tie se je. Eyi ko sai
ran an lowo lati ko awon omo e naa sidii oselu, ti idile awon Saraki si se bee
di gbongbo nla kan ni Kwara, toro ba doro oselu.
Lodun 1999 ni oselu bêre pada ni Nigeria, bee ni agbara
Olusola Saraki naa n peleke si i ni Kwara, o si fe ma si ibi kan bayii nipinle
ohun ti won ko ti mo pe, bi enikeni ba fe gbe igba oselu. nile awon Saraki lo
gbodo lo, ki won ba a fowo si i.
Lodun 1999 ni Gbemisola Saraki
darapo mo oselu, nigba ti oselu bere pada, ipo asoju-sofin lo lo fun niluu
Abuja, nibi to ti n soju fun ekun idibo Asa/Ilorin. Nigba to si tun di odun 2003, o tun gbapoti ibo, bee lo se di
asofin agba, iyen seneto ni Nigeria. Bakan naa ni egbon e, Dokita Bukola Saraki
naa di gomina ipinle Kwara lodun 2003.
Egbon di gomina, aburo si di
seneto, bi awon omo Olusola Saraki naa se darapo mo oselu ree, ti ipo won ninu
oselu Nigeria si n bureke si i.
E maa ba wa ka lo…
0 Comments