GBAJUMO

BABANGIDA KI BUHARI KU ORIIRE, O NI KO TETE GBOGUN TI AWON BOKO HARAM *BEE LO RO ATIKU KO GBA F’OLORUN


Aare orile-ede yii tele laye ijoba ologun, Ibrahim Badmosi Babangida ti ki Muhammed Buhari ku oriire aseyori e ninu ibo to koja.
Ana ode yii ni Ajagunfeyinti Ibrahim Babangida naa pelu awon eeyan pataki kaakiri agbaye ti won ti n ki Buhari ku oriire. Bee lo ro o ko tete wa ojuutu si idaamu tawon Boko Haram n ko ba awon omo Nigeria loke oya.
Ninu oro e naa lo ti ke si Buhari wi pe ko gbiyanju sise takuntakun lori bi atunto to ye yoo se ba eto isakoso lorile-ede yii, ti ekarika akoso ijoba naa yoo le sanafani to peye fun araalu. 
Bee lo fi kun un wi pe oro awon onisunmomi ajinigbe, awon adigunjale atawon alajangbila Boko Haram yoo se dohun amupitan ni Nigeria.
Babangida so pe, oro awon eeyan yii n ko idaamu nla ba awon omo orile-ede yii, paapaa loke oya lohun-un nibi ti won ko ti i le foju kan oorun latari bi awon Boko Haram se maa n ya wo ilu ati ileto, ti won yoo si se opo emi oun dukia lofo repete.
O ni, oro awon ajinigbe naa se pataki lati je ohun amojuto, ati awon adigunjale paapaa, ati pe o gbodose amojuto to peye lori bi oro aje Nigeria yoo se dara si i.
Siwaju si i, Babangida ti ro Alhaji Atiku Abubakar, oludije fun ipo aare labe asia egbe oselu PDP lati fowo wonu, ki o si ba awon ololufe e soro, ki won ma se gba esu laaye latari esi ibo ti ko se igbakeji aare tele yii loore.
Ninu oro e naa lo ti ki i lori igbiyanju e, bee lo ro o, ko gba fun Olorun ko si fowo-sowopo pelu Buhari lati mu Nigeria te siwaju.

Post a Comment

0 Comments