GBAJUMO

BI DOKITA BUKOLA SARAKI SE GBA AGBARA OSELU LOWO BABA E NI KWARA *ASIRI OHUN TO DA WAHALA NLA SILE LAARIN OUN ATI GBEMISOLA, ABURO E

           APA KEJI
Boro se wa ree ki wahala too be sile lodun 2011 nigba ti Bukola Saraki pari saa e, iyen odun mejo gege bi gomina ipinle Kwara. Bi Bukola se n mura lati gbe ijoba sile lo ti ni in lokan lati gbe e fun eni to se komisanna eto isuna e, Abdul-Fatah Ahmed fun bi odun mejo.
Bi Saraki se n ro eyi lokan, bee ni Gbemisola ati Dokita Olusola Saraki, eni ti se baba won naa ni ohun to wa lokan tiwon naa, paapaaa lori bi Seneto Gbemisola Saraki yoo se di gomina ni Kwara.

Oro yii di wahala repete, bee lo dohun ti Oloye Olusola Saraki ati Seneto Gbemisola Saraki fi egbe oselu PDP sile fun Bukola, ti won si lo da egbe kan sile, ti won n pe ni egbe olokere, iyen ACPN.
Lara ohun ti won fi n polongo ibo tako Gbemisola Saraki nigba yen ni pe, ilu Alfa niluu Ilorin, ati pe yoo soro ki obinrin je asaaju awon nibe. Bo tile je pe ki i se Ilorin nikan ni won ti fe dibo yan an gege bi gomina, sibe ariwo ti won n pa kiri niyen, bee ni won tun n so pe ko le see se ki egbon kuro nile ijoba, ki aburo e naa tun gba a.
Eyi lo fe je isoro akoko ti Oloogbe Olusola Saraki maa dojuko nidii oselu ni Kwara, nibi ti oun ati omo e to bi ti jo n mu nnkan nile nidii oselu.
Baba fe ki omo e obinrin se gomina, bee lomo e okunrin naa n ti okan lara awon to ba a sejoba fodun mejo siwaju lati gba ipo lowo e, n loro ba di dukuu, ti won bere si korin ote oselu kaakiri ipinle Kwara.
Oro yen gan an lo le Turaki Ilorin, iyen Oloye Olusola Saraki kuro ninu egbe oselu PDP, n ni baba ati omo e Gbemisola ba lo da egbe mi-in sile, egbe olokere, iyen ACPN.
Pelu gbogbo akitiyan ati igbiyanju won, sibe Abdul-Fatah Ahmed lo jawe olubori, ti Bukola Saraki si se bii ogbon gba ipo agbara oselu Kwara mo baba e lowo.
Nibi ti idaamu ti koko ba ile awon Saraki niyen o, ija ohun ko si tan nile titi doni laarin Bukola ati aburo e ti ipo gomina wu lodun naa lohun-un. Latigba yen gan-an ni kaluku ti n se tie loto.
Ko pe sigba yen ni aisan kolu Oloye Olusola Saraki, lojo kerinla osu konkanla odun 2012 ni erin nla wo niluu Ilorin, Oloye Olusola Saraki lo jade laye, bi Bukola Saraki se deni ti gbogbo Kwara n wa ri fun ree toro ba doro oselu.
Ni tododo, awon eeyan kan so wi pe asaaju ni omobinrin yii, iyen Gbemisola je nidii oselu, nitori lati odun 1999 lo ti wa niwaju lasiko igba to lo se asoju-sofin, nigba yen, Seneto Bukola Saraki ko ti i wo inu oselu ni tie, odun 2000 lo darapo mo ijoba Obasanjo.

Lodun 2015 ni Emir ilu Ilorin Oba Ibrahim Sulu Gambari pe awon mejeeji yii, Seneto Rukoya Gbemisola Saraki ati egbon e, Bukola, oba alaye yii lo petu si won ninu wi pe ki won ma bara won ja mo, ki won je ki agboole won wa nisokan.

Bo tile je pe lojo naa lohun-un, bi won ti kuro laafin Emir ni won jo wonu moto kan naa, ti won gba ile baba won lo, sibe oro oselu ti tu won lasiiri, bee lo foju han wi pe, ikunsinu yen si wa nibe daadaa.
E MAA BA WA KA LO…




Post a Comment

0 Comments