GBAJUMO

IJOBA SARAKI TO WO NI KWARA, WON LO SEE SE KAWON EEYAN PADA KABAMO E

APA KERIN
Ohun ta a gbo ni pe, agbo oselu nla ti okunrin yii jogun lowo baba re, asiko igba kan wa ti ko mojuto o daadaa mo, ati pe nibe gan-an ni wahala ohun ti bere diedie, ti ota fi raaye wole si i lara.
Ohun ta a gbo ni pe, awon mudun-mudun ijoba ti okunrin oloselu yii maa n pin fawon alatileyin e, won ni lawon asiko kan, nise ni awon to maa n fi awon nnkan ohun ran sawon eeyan bere si lo o funra won, ti won ki i fun awon eeyan ti okunrin Seneto yii ni ki won ba oun fun mo. Won ni bi won se n fun awon ore, ni won n fun awon ara ati ojulumo won, ti awon ti won letoo si i; ko si ri mudun-mudun kankan je mo.
Yoruba bo, won ni oloro abi eti didi, bi won se n pin kinni yii fawon to je tiwon, ti awon naa n fela ninu e, bee loro ohun n da wahala sile lawon ilu ati ileto, sugbon ti Seneto Bukola Saraki ko mo ohunkohun ni tie rara.   
Dipo bee, iro ni won n pa fun un, ti won si n so pe, ko si enikan bayii to le gba Kwara lowo awon, Bukola omo Saraki lo si ni kokoro gbogbo Kwara lowo.
Oro ti won n so fun un ree o, bee ohun ti yoo maa dunmo ninu nikan ni won n je ko gbo, ti inu okunrin oloselu yii naa si n dun gidigidi wi pe, ti ibo ba de lodun 2019, nibe gan-an loun yoo ti ko awon Tinubu ati Lai Muhammed ti won n pariwo O TO GE kiri logbon daadaa. Nigba ti oro ohun yoo tun le si i, won ni; nise ni Saraki gan-an ko boju weyin lati mo bi eto se n lo si, nise lo nigbagbo nla ninu awon eeyan ti won n tan an wi pe oun lo si ni ikawo Kwara lowo.  
Sa o, nigba ti oro ohun yoo ye e si, omi ti teyin wo igbin lenu, nitori pupo ninu awon ohun amayederun to pese fawon araalu ti won n fe tie, nise lawon omo eyin e yii ti ta won danu, ti won nawo je ni tiwon, ti awon eru ohun ko si lo sibi to ye.
Isele yii gan-an lo sakoba nla fun Saraki lojo ti awon omo egbe oselu APC yawo ilu Ilorin pelu orin O TO GE, ti oludjie fun ipo gomina nipinle naa bayii, Abdul-Rasaq Abdul Rahaman n pa kiri wi pe ki won pada leyin awon Saraki nitori nise ni won n tu won je bii isu.
Lojuese lawon ti inu n bi tele naa ti digba-dagbon won, ti won si ba awon yen lo ni tiwon.
Ohun ti won lo tubo koba idile oloselu yii ni bi awon eeyan e kan ti won ti mo gbogbo asiri ti awon Saraki maa n lo fi jawe olubori ni Kwara se binu kuro lodo e, sugbon ti okunrin seneto yii ko lati wa ojuutu si wahala to sele laarin won.
Awon eeyan yii gan-an ni won so pe won lo sise fun awon ota Saraki, ti won si ko gbogbo asiri bi okunrin naa se n dari oselu Kwara ati eyi ti baba re ti n lo tipe le awon omo egbe oselu APC lowo, eyi to won fi reyin e nigbeyin oro.
Okan lara awon onisowo nla ni Abdul-Razaq Abdul Rahaman, eni to wole sipo gomina nipinle Kwara bayii. Saaju asiko yii lo ti koko darapo mo egbe oselu awon Muhammed Buhari, iyen CPC lodun 2007, nigba to ba Bukola Saraki dupo gomina sugbon to fidi remi.
Lodun 2011 bakan naa, won lo tun jade fun ipo seneto labe asia egbe oselu PDP, sugbon ti nnkan ko senuure fun un nigba yen naa lohun-un.
Ijakule yii gan-an ni won lo mu awon to sunmo on daadaa ro o wi pe ki o fi oselu sile, ko koju mo ise e to so o di olowo repete. Sa o, ajosepo ti oun ati Aare Muhammed Buhari ti ni tele ninu egbe CPC ko sai ran an lowo nigba ti eto idibo tun bere, eyi to fun un lanfaani lati ri tikeeti gba lati dije fun ipo gomina bayii. Bo tile je pe lojiji lawon eeyan bere si gbo ariwo O TO GE kaakiri ipinle Kwara, won ni o ni bi oro ohun se bere gan-an. 
Awon eeyan kan ni won ko ara won jo lati fehonu won han lori eto idibo kan to waye lodun 2017. Ibo alaga ijoba ibile lo waye ni kansu Iwo-oorun Ilorin (Ilorin West), ninu eyi ti won ti so pe Alhaji Musibau Esinrogunjo lo jawe olubori, oun atawon kanselo mefa ti won jo wa ninu iko kan naa. Nigba ti ajo eleto idibo ipinle Kwara ko lati kede okunrin yii atawon eeyan e lawon eeyan kan ko ara won jo lati wode kaakiri Ilorin. 
Bee ni won ya lo si ofiisi ajo eleto idibo Kwara, KWASIEC lati fehonu won han. Lojo ti a n yii, won fere da nnkan ru patapata mo ijoba lowo nigboro Ilorin, bi won se n laagun yobo, bee ni won n sepe repete, ti won si n pariwo O to ge.
Lasiko iwode yen gan-an ni oro yen ti koko jeyo, tawon eeyan si n korin kiri wi pe O to ge, awon ko ni i singba labe isakoso awon Saraki mo ni Kwara.
Ni kete ti eto ipolongo ati oselu tun bere pada, nibe gan-an ni awon eeyan tun ti mu oro yen jade wi pe, akomona tawon yoo lo lati fi bi ijoba awon Saraki wo ni Kwara ni O TO GE!
Ninu ipade orisirisi ti won se ni okan lara awon agba oselu nipinle Kwara, Alhaji Lasisi Jimoh, eni tawon eeyan tun mo si L.A.K Jimoh, okan lara awon eeyan ti ko faramo irufe oselu tawon Saraki n se ni Kwara ti mu aba ohun wa wi pe akomona tawon yoo fi bi ijoba Saraki wo ni Kwara ni O TO GE!
Okunrin oloselu yii, to tun je onkowe nla so pe ti won ba le fowo si i ki awon maa lo O TO GE gege bi akomona nibi ipolongo ibo, eyi yoo je oro itaniji fawon eeyan Kwara, bee lo see se ko mu opin de ba ijoba Saraki nipinle ohun.
Bi wolii lokunrin oloselu yii se soro lojo naa, nni won ba tewo gba a lowo re, ti oludije fun ipo gomina paapaa, Alhaji Abdul Razak Abdul-Rahman naa si gba a gege bi akori oro tawon yoo maa lo nibi ipolongo ibo, bee lawon omo egbe oselu APC naa fowo si i wi pe oun gan-an lawon yoo maa fi polongo ibo. Bi won se tewo gba oro ohun ree nile Ilorin, bee ni ko pe pupo ti oro yii fi dohun tawon eeyan n so kaakiri ipinle Kwara atawon ilu nla nla tawon omo Kwara wa kaakiri Nigeria ati loke okun paapaa.
Bi won ti se n so o loro, bee ni won n ko o lorin, tawon lolokada atawon oni-takisi n’Ilorin paapaa n fi fere moto ati okada won pariwo O TO GE ti won ba ti pade ara ni popo.
Were bayii loro ohun bere, bee lo ti wo awon eeyan Kwara lara daadaa, ti asa O TO GE ti gbale gboko; ki awon omo egbe oselu PDP too mo pe oro ti be yin yo.
Lati le pana asa O TO GE yii, lojuese lawon eeyan Saraki naa wa oro kan ti awon naa le maa pariwo e kiri igboro, nibe gan ni gbolohun O TUN YA ti je jade, sugbon bi awon eeyan se n ba awon Saraki wi i to, nise ni won n yinmu si won, nigba ti ojo idibo aare ati tawon asofin agba si dele, gbangba-gbangba lawon eeyan ipinle Kwara fi ibo pariwo fun gbogbo agbaye wi pe O TO GE, ijioba Saraki ni Kwara, awon ko fe e mo.
Bi awada lawon eeyan koko pe e nigba ti esi ibo n jade ti awon omo egbe oselu APC n rowo mu, tawon eeyan Saraki n fidi remi.
Nigba ti won yoo si fi kede wi pe APC lo wole, ariwo O TO GE yipada lojiji, n lawon eeyan ba bere si pariwo O TOPE.
Ju gbogbo e lo, APC ti wole ni Kwara, Saraki paapaa naa ti gba fun Olorun wi pe ileri e lo se.
Sugbon o, bi APC yoo se dari ipinle ohun, ti iyato nla tawon omo Kwara n reti yoo se sele laarin odun merin mi-in, ki eto idibo mi-in too tun waye, oju ree iran ree.

Post a Comment

1 Comments

  1. Sebi awon eeyan re naa loso doloriburuku, bi teni kan o ba baje teni o le da, eyii ti Saraki naa se n gbe naa to

    ReplyDelete