Ile ejo giga kan niluu Akure ti pase pe ki won lo yegi fun Seidu Adeyemi, eni to seku pa omo igbakeji gomina ipinle Ondo tele, Khadijat Oluboyo.
Akekoo Yunifasiti Adekunle Ajasin to wa ni Akungba-Akoko, ni Khadijah n se, ipele to keyin ninu eko e gan-an lo wa ki Seidu to seku pa a nile e to wa ni Oke Aro niluu Akure lojo keji osu keje odun to koja.
Ni bayii, won ti dajo wi pe ki won lo yegi fun Seidu Adeyemi titi ti emi yoo fi bo lara e.
0 Comments