Ninu ibanuje nla lawon akekoo ti won n ko nipa eko isegun oyinbo
wa bayii lori bi awon janduku kan se gun akegbe won pa l’Ekoo.
Ohun ta a gbo ni pe, Dokita Stephen Urueye naa wa lara awon
akekoo ti won sese pari eko won nileewe giga Lagos University Teaching Hospital
(LUTH). Won ni lasiko to n lo sile, leyin ayeye ikekoo jade ohun lawon janduku
kan kolu, ati pe nibi ti won ti fe ji awon nnkan ini e ko ni won ti gun un
lobe, ti okunrin sanmori Olorun yii si se bee ku lojuese.
Ojoru Wesde to koja loun naa pari eko e ni Yunifasiti Eko, iyen
UNILAG. Won ni lojuna Idi Araba ni Musin lagbegbe ileewe e ni won ti kolu u lojo
Ojobo, Tosde ana, ti won si se emi e lofo.
Eyi gan-an ni won lo bi awon akegbe e ti won ti n pariwo fawon
alase ileewe naa tele wi pe janduku maa n yo awon lenu ju lagbegbe ohun ninu,
ti won si bere iwode lati fehonu won han lori iku ojiji to pa okunrin yii.
0 Comments