GBAJUMO

SECONDUS ALAGA PDP KO AWON OMO EGBE E LOO DOBALE NILE OBASANJO

...WON NI BABA, E DARIJI WA, A MO PE A SEYIN GIDIGIDI
Bi eto idibo odun 2019 se n sunmo, ti awon egbe oselu n wa gbogbo ona lati fibo le Aare Muhammed Buhari kuro, igbese tuntun mi-in ti egbe oselu PDP tun gbe ni bi won se wa Oloye Olusegun Obasanjo lo sile re niluu Abeokuta, nibi ti won ti lo toro aforiji lowo olori orile-ede yii tele.

Fun bii wakati meji aabo ni Alaga egbe oselu PDP atawon omo igbimo e ti gbogbo won je mokanlelogun atawon agbaagba ninu egbe ohun jo tilekun mori sepade pelu Oloye Obasanjo.
Oloye Uche Secondus, alaga PDP, Oloye Obasanjo
ati die lara awon omo egbe PDP ti won wa bebe
Ni kete ti won pari ipade ohun ni Oloye Uche Secondus eni ti se alaga PDP ba awon oniroyin soro, ohun to si so ni pe, asaaju gidi ni Obasanjo n se, ati pe awon wa ba okunrin naa jiroro lori bi ojo orile-ede yii yoo se dara ni.
Ninu oro Oloye Bode George ni tie lo ti so pe, “Ko ye ki a tun tan ara wa je mo niru asiko yii. Ibeere ti mo lero pe o ye ki a bira wa lori-ede yii ni pe, nje ana wa dara ju oni lo bi? Iru ipo wo ni a wa lana-an, bawo ni igbe aye wa se ri loni-in? Ohun to ye ki a a bira wa niyen o. Ti a ba si wo ipo ti Nigeria wa bayii, eni to ba mo aato ilu gan-an lo ye ki a gbe isakoso e le lowo. A ko tun gbodo maa tan ara wa je mo.”
Egbe oselu PDP so pe nise lawon wa toro aforiji lowo Oloye Obasanjo nitori pe awon gan-an mo lokan ara awon wi pe awon se baba naa gidigidi.
Te o ba gbagbe, bi eto idibo odun 2015 ti n sunmo etile ni wahala nla be sile ninu egbe oselu PDP, nita gbangba ni Aare tele lorile-ede yii, Oloye Olusegun Obasanjo ti fa kaadi to fi i han gege bi omo egbe ohun ya. Bo ti se eyi tan lo kede wi pe Buhari loun n ba a lo, sugbon ki i se pe oun fe darapo mo egbe oselu kankan.
Awon omo egbe oselu PDP ti won wa bebe ree,
Omooba Olagunsoye Oyinlola naa wa nibi ipade ohun
Nibe yen gan-an ni idaamu nla ti ba egbe oselu PDP, ti Aare Jonathan to dije loruko egbe naa si se bee fidi remi lodun naa lohun-un. Yato si Obasanjo to fi egbe naa sile, opolopo omo egbe oselu ohun ti won wa nile igbimo asofin agba, awon to wa nile igbimo asoju-sofin atawon gomina ni won ya kuro ninu egbe ohun lo da egbe oselu APC sile, latigba naa ni egbe oselu PDP to ti n dari ipo aare orile-ede yii bo lati odun 1999 ti wa nipo alatako, ti nnkan si se bee daru mo won lowo.

Ni bayii ti eto idibo odun 2019 ti n sunmo, ti egbe oselu bii ogbon ti so pe awon setan lati komolupo-bo pelu egbe oselu PDP lati le Aare Muhammed Buhari kuro, ohun tawon eeyan n so ni pe, oju ree iran ree lori ibi ti igbese ohun yoo yori si.

Post a Comment

0 Comments