Ileeṣẹ to n ri si ipolongo
Atiku Abubakar fun ti ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP ti sọ pe ko si ootọ ninu ahesọ ọrọ kan tawọn kan n gbe e jade pe ọkunrin naa ti n mura
lati fẹgbẹ oṣelu naa silẹ lọ darapọ mọ ẹgbẹ mi-in, wọn ni irọ to jinna sootọ ni.
Ninu atẹjade kan ti Ọgbẹni Ṣẹgun Ṣowumi, to jẹ agbẹnusọ olupolongo fun ileeṣẹ naa gbe jade lọjọ Aiku Sannde, ana
lo ti sọ pe awọn to n gbe igbekugbe naa jade ko niṣẹ ati pe nnkan ti
wọn ko ri i ni wọn
n sọ lati yi ọkan awọn alatilẹyin ọkunrin naa pada ni wọn n ṣe e, eyi to sọ pe wọn ti mu ofo ọjọ keji ọja.
O ni fawọn alaigbagbọ, ko sigba kankan ti
Atiku pinnu lati fẹgbẹ naa silẹ, bẹẹ si ni ẹsẹ ẹ ko yẹ lati dije fun
ipo aarẹ to n bọ lọdun 2019. O
ni lati nnkan bi oṣu meji sẹyin lọkunrin naa ti n rin
irin-ajo kaakiri orilẹ-ede yii lati fi
ipinnu ẹ han.
O ni titi di akoko yii
lawọn alatilẹyin ẹ ṣi
n fi ifẹ wọn han si i pe ko maa niṣo o, awọn wa lẹyin ẹ nibi ibo pamari ti yoo
kọkọ waye. Ileeṣẹ olupolongo naa ti ke si awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP pe ki wọn fọkanbalẹ ki wọn ma jẹ kawọn onisọkusọ ba ero ọkan wọn je. Idaniloju si wa
pe lọdun to n bọ Atiku ni yoo di aarẹ orile-ede Nigeria.
0 Comments