Ninu osu keta odun yii ni awon janduku egbe BOKO
Haram kogun ja gbegbe kan ti won n pe ni Rann, Kala Balge, nibe lowo won ti te awon osise ajo Red Cross, iyen
alagbelebu pupa, ninu eyi ti Hauwa Liman ti wa lara won, ti won si ti yinbon pa
a bayii.
Egbe BOKO Haram kan ti won pe oruko won ni Islamic
State West Africa Province (ISWAP), lo yinbon pa arabinrin naa. Won ni seni won
so o lokun lowo seyin, ti won da a kunle, ti won si se bee yinbon fun un
lateyin.
Saaju asiko yii ni won ti koko pa enikan danu, Saifura Ahmed loruko e, lara awon osise
Red Cross ni. Ni kete ti won ti pa a ni egbe alajangbila yii ti so fun ijoba apapo
wi pe ti won ko ba fun awon lohun tawon n fe, nise lawon yoo pa Hauwa Liman naa.
Ana Monde yii ni gbedeke ojo ti won fun ijoba apapo
tan, nigba ti ile yoo fi mo laaaro Tusde oni, ariwo to gbalu kan ni pe, won ti
gbemi obinrin osise ajo Red Cross ohun.
Esun ti won fi kan Saifura ati Hauwa enikeji e ti won ti koko pa tele ni pe, won
pa esin Islam ti, won ba ajo agbelebu lo, eyi to mu egbe alajangbila ohun ka
won kun odale .
Ijoba orile-ede yii ti bu
enu ate lu iku ojiji ti won fi odomobinrin naa. Ninu oro ti minisita feto
iroyin, Alhaji Lai Mohammed fi sowo lati ilu London to wa lo ti so pe iku
obinrin naa ba ijoba apapo lojiji, ati pe iyalenu nla lo je wi pe awon alajangbila
ohun le pa a pelu gbogbo akitiyan ti ijoab sa lati ri i pe won tu oun atawon
yooku e sile nigbekun awon odaran ohun.
Te o ba gbagbe ko ti ju osu
kan lo ti awon alajangbila yii sekupa Saifura Ahmed, latigba naa ni won si ti
fun ijoba apapo ni gbedeke igba ti won yoo tun pa elomi-in ninu awon osise ajo
Red Cross ti won wa nigbekun won.
Lara awon to si wa nigbekun
won bayii ni Alice Ngaddah, elesin Kristeni ni, bee lo tun je osise ajo agbaye
kan to n je UNICEF.
Bakan naa ni Leah Sharibu,
okan lara awon omoleewe Government Girls’ Science and Technical College, niluu Dapchi,
ipinle Yobe State. Eeyan Aadofa (110) ni won lo ji gbe nileeewe ohun lojo naa,
obinrin si ni gbogbo, iyen lojo kokandinlogun osu keji odun yii. Leah Sharibu
nikan lo si wa ni akata won, nigba ti won ti tu awon yooku sile.
Ohun ti won lo fa a ti won ko
se fi i sile ni bi odomobinrin ohun se ko lati gba esin Islam, won lo so pe esin
Kristeni toun n se loun ba duro. Ohun ti won lo bi awon alajangbila yii ninu
niyen o, ti won ko fi ju u sile nigba ti won yonda awon yooku e fun ijoba.
Ni bayii, leyin ti won pa
Hauwa, ohun ti won n so ni pe, Leah Sharibu ti di eru awon bayii, ati pe gbogbo
ara to ba wu awon pata la won yoo fi omo naa da.
0 Comments