Bi eto idibo pamari fun ipo gomina se n lo lowo, igbakeji
gomina Eko, Alhaja Idiat Adebule ti pada leyin oga re, Akinwunmi Ambode, eni ti
won jo n fa ipo naa mora won lowo, Babajide Sanwo-Olu lo ba lo.
Lasiko ti oun naa fe dibo yan eni ti yoo soju egbe ohun
laarin Akinwunmi Ambode ati Babajide Sanwo-Olu ni wooodu A ati D nijoba ibile
idagbasoke Iba l’Ekoo lo soro ohun.
Dokita Idiat Adebule ti so fawon oniroyin wi pe, “Egbe wa ti
fa eeyan kan kale, eni ti egbe si fa kale ni mo setan lati dibo mi fun.”
Igbakeji Gomina Akinwunmi Ambode ni obinrin oloselu yii n se
ninu ijoba ti won n se lowo.
Ohun ta a gbo ni pe, posita Babajide Sanwo-Olu ni awon
alatileyin obinrin oloselu yii gbe lowo, bi won se de gbagede ti eto idibo ohun
ti n waye lawon eeyan ti n ri i lowo won yee-ye-e-ye.
Yato si eyi, Asiwaju Bola Tinubu naa ti so pe, ohun abuku
loun yoo ka a si ti enikeni ba so pe wahala wa laarin oun ati Gomina Ambode.
Okunrin oloselu yii soro yii lasiko ti oun naa dibo feni to fe ko jawe olubori
ninu ibo pamari ti egbe naa n di loni-in.
Tinubu so pe, “Osise ijoba ni Ambode, emi ti mo mu un wonu
oselu ree nigba to pari eko e nipa oselu ni Harvard. Bo se de lo fi ife han
lati darapo mo oselu, a si gba a laaye, nitori eni to sise takuntakun gege bi
osise ijoba ni; lasiko ti mo wa nipo gomina. Awa naa la kede e fun araalu ti won
si tewo gba a. Ohun to n sele nisinyi koja oro emi nikan, oro egbe ni, ibi ti
egbe ba si n lo la gbodo tele.
Titi di bi a se n ko iroyin yii jo, opo awon agbegbe ni won
ti pari ibo pamari won, bee Babajide Sanwo-Olu lo si n jawe olubori.


0 Comments