GBAJUMO

RASHEED, OMO AJIGIJAGA ONITIATA FE DANA ARIYA REPETE L’EKOO


Sannde, ojo kejidinlogbon osu yii ni gbajumo olorin fuji nni, Rasheed Okanlawon Ajigijaga yoo se ikojade rekoodu e tuntun to pe akole e ni 50/50.
Okan lara awon olorin fuji ti won n se daadaa nidii ise orin l’Ekoo, paapaa niluu Agege ni Rasheed, eni tawon eeyan tun mo si Emir n se. Rekoodu to fe gbe jade yii ni yoo je eleekarun-un to ti se.
Lara awon rekoodu to ti gbe jade niwonyi; Aristo; Permutation; Alujo tuntun; My parent, ni bayii 50/50 lo fe gbe jade bayii.
Ninu oro e lo ti so pe, “Ojo nla to maa larinrin lojo yen, se e mo pe omo osere tiata lo n se nnkan, gbogbo awon eeyan nla nla ni won n bow a ye wa si, paapaa awon ololufee baba mi Ajigijaga naa; won ko ni i gbeyin lojo yen. Alagba Sulaimon Ayilara, eni tawon eeyan tun mo si Ajobiewe ni yoo ko awon osere tiata yooku sodi wa. Lara awon ti won n bo ni Hafeez Owoh atawon osere nla nla mi-in nidii ise sinima.
Bakan naa lawon agba oje nidii ise sorosoro bii, Banjo Ojedeji; Yeye Bidemi Olukuewu atawon mi-in naa yoo peju pese pelu wa
Ile-itura R.V Unique event centre, lagbegbe Orile-Agege l’Ekoo lo so pe ayeye ohun yoo ti waye. Aago mejila osan ni eto yoo ti bere, nibi ti gbogbo awon olorin fuji pata yoo ti peju-pese ba Emir sajoyo nla yii. Adeoye Afefe Oro ati MC Biggy ni won yoo jo dari eto lojo yen.

Post a Comment

0 Comments