Foto kan ti gbogbo iwe iroyin n
gbe bayii ni foto ibi ti Aare Muhammed Buhari ti duro, ti okan lara awon oga
agba ileese to n mojuto idanwo asekagba oniwee mewaa, Dr. Iyi Uwadiae, iyen
WAEC ti fun un ni iwe eri moyege.
Bi foto ohun ti bo sigboro
lawon eeyan kan ti n so pe, o ya baba na, won ni o se je leyin bii aadota odun
ni won too fun un niwe eri tie.
Sa o, Aare Muhamed Buhari ti
soro o, ohun to si so ni pe, kani oun ko jokoo se idanwo ohun lodun 1961 ni,
pelu awon eeyan bii Oloogbe Sheu Musa Yar’ Adua oun ko ni i lanfaani lati lo
kawe si i ni India lodun 1973 ati ni Amerika lodun 1979.
O ni, odun mesan-an gbako loun
ati Yar’Adua fi jo kawe pamari ati iwe mewa pari, ti awon si tun jo te siwaju
lati darapo mo ileese oloogun orile-ede yii.
Buhari ti wa dupe lowo ajo WAEC
ti won ba pa enu awon elegan mo, pelu bi won se mu iwe eri ohun le e lowo, eyi
to ti fihan bayii wi pe, loooto ni aare ni iwe eri iwe mewaa lowo.
Bakan naa ni ileese aare ti so
pe, igbese to ye ni ajo WAEC gbe lori bi won se fidi e mule wi pe loooto ni
Buhari kawe mewaa jade. Won ni, bi awon egbe oselu alatako se n gbe e kiri, oro
ohun ti fe maa ba ijoba Buhari loju je.


0 Comments