Falake Z. Adejumo, eni tawon
eeyan tun mo si Emily onikaba loruko iya to
sese ku yii, eni odun metadinlogorin (77) ni, ki olojo too pe e sodo.
Okan lara iyawo Baba Sala ni
mama yii, bee lo tun je ojulowo osere leyin oko e. O fe ma si ere ori itage
tabi sinima mi-in ti Baba Sala se nigba aye e, ti oruko Emily Onikaba ko ni i
han ketekete ninu e.
Ana, ojo kokanlelogbon
osu kewaa odun yii ni Oloogbe Falake Z. Adejumo jade laye, gege bi atejade ti
okan lara awon oloogbe naa fi sori afefe, bakan naa ni eto isinku e ti bere
loni-in ojo kin-in-ni osu kokanla odun yii.
Isin asale onigbagbo ni
won yoo se fun un nile e ni 19, Obasekonla, Oke Ogun street, Owo nipinle Ondo.
Aago merin irole ni won so pe ero ohun yoo bere, nigba ti won yoo sin in lola
Fraide ojo keji osu kokanla.
Awon ebi ti so pe
laipe yii lawon yoo maa kede eto ayeye isinku naa.
0 Comments