Lojo Eti, Fraide to koja ni
isele ohun sele niluu Eko, gbajumo olorin esin Islam nni, Alhaji Ahmad
Najemudeen Alawiye, eni tawon eeyan tun mo si Alalubarika lo ko ileese tuntun
jade, ise hajj ati Umrah ni won n se nibe.
Awon agbegbe kan l’Ekoo ni
gbajumo olorin yii atawon akegbe e nidii ise orin ti se iwode ita gbangba lati
polongo ileese tuntun ti Alawiye sese da sile yii fun ise hajj to peye.
Ninu oro gbajumo olorin esin
Islam yii lo ti so pe, “Gbogbo ohun ti a n se nileese wa, pelu iberu Olorun ni
o.
A segbekale ileese yii fun ise hajj to peye, ki awon Musulumi le ri ise hajj
se nirorun, bee ni gbogbo ohun amuye pata to le mu un rorun fun won pata wa ni
ikawo wa. Opo eeyan lo ti ba wa lo nigba kan, emi ni mo ko won sodi lo si Mecca
lodun to koja, gbogbo awon eeyan yii ni won si le serii wi pe nileese tiwa,
iberu Olorun ati ipaya e la fi n se ohun gbogbo ti o fi n bo si i fun wa.
Oloruko gidi ni wa laarin ilu, bee la o ni i se ohun to maa ba wa loruko je,
tabi to maa tabuku ba esin Islam,esin asinla ta a gbe dani.”
Alawiye ti so pe anfaani ti si
sile fun gbogbo Musulumi ti won n gbero lati lo si Mecca fun ise hajj tabi
Umarah lati tete wa darapo mo ileese Al-Hatyku bayii, ati pe gbogbo anfaani
pata ni won yoo letoo si i ninu irinajo oriire naa.
Lara awon gbajumo olorin Islam
ti won jo se iwode ohun ni Alhaja Rukayat Alawiye Basirimi, Alhaja Fatimo Iyawo
Facebook; Ibrabim Adebayo Wahab eni tawon eeyan tun mo si Hyb Addis atawon olorin mi-in pelu, bee lawon ololufee Alawiye, ti oruko
egbe won n je ALALUBARIKA FAMILY naa wa nibi iwode ita gbangba naa, orin ti won
si jo n ko ni pe; Al-Hatyku lawon eeyan gbodo tele lo si Mecca ati Medina fun
ise hajj to peye.





0 Comments