Ninu atejade ti okunrin
onitiata yii fi sowo sori okan lara ero alatagba e, iyen Instagram lo ti fi
idunnu nla yii han.
Lori ikanni ohun lo ti so pe, “Eyi
ni aseyori ohun ti a ti n reti, bee lo mu ayo wa kun gidigidi. Emi gan-an ni
inu mi dun, ti ayo mi si kun pelu. Omo wa oloriire ti de o! Okunrin lantilanti
ni paapaaa! E ba wa yo, e ba wa dupe lowo Olorun oba. Ife mi si o, Iyanaladuke mi owon po jojo, mo dupe lowo Olorun fun irin-ajo alaseyori yii…”
Ni kete to ti fi oro yii sori
ikanni re lawon osere egbe e ti lu ikanni ohun pa, nibi ti won ti n fi
orisirisi oro ikinni ku oriire ranse si oun ati molebi e.
Bi a ti se n ko iroyin yii jo,
awon eeyan lolokan-o-jokan ti won ti ki Femi Adebayo ku oriire ti fe to egberun
kan, bee lawon mi-in si n wole si i.
Te o ba gbagbe, odun 2016 ni
Femi segbeyawo pelu iyawo e tuntun yii, iyen Maimunat. Won lo se die ti awom
mejeeji ti n se wole wode ki oro ohun too yori si igbeyawo alarinrin lojo
kesan-an osu kewaa odun 2016.



0 Comments