Tosde, ojo kefa osu kejila odun yii ni gbajumo ojise Olorun
nni, Daniel Ebelamu Ajibose yoo gba opa ase gege bii baale ilu Olota, nijoba
ibile idagbasoke Agbado Oke Odo, l’Ekoo.
Ninu iwe ti ijoba ibile Alimoso fi sowo si i lojo
ketadinlogun osu kewaa odun yii ni akowe ijoba ibile ohun, Olaleye M.A ti fidi
e mule wi pe, Ogbeni Daniel Ebelamu Ajibose gan-an ni igbimo to n ri si oro oye
nijoba ibile ohun fowo si gege bi baale tuntun niluu Olota.
Ninu iwe ohun ni won ti fidi e mule wi pe, awon meji ni ebi
Adibo fa kale, Ogbeni Fehintola Akanni ati Daniel Ajibose, ti won jo du oye
ohun, ki o too ja mo Ajibose lowo, leyin ti igbimo to n ri si oro oye se iwadii
to peye.
Odun 1967 ni won bi Oloye Daniel Ebelamu Ajibose, akosemose
onimo ero ni, iyen Enjinnia, bee lo tun je ojise Olorun to maa n se waasu ati
ihinrere nipa Olorun ati Jesu Olugbala. Lose yii gan-an la gbo pe won yoo fun
un lopa ase, ti yoo si bere si dari ilu Olota ni Agbado Oke Odo, l’Ekoo.


0 Comments