Kaakiri ori ero ayelujara ni won ti n ki awon toko-tiyawo
yii ku ewu. Bi awon osere egbe e se n ki won ku ayo omo, bee lawon ololufe
Funke Akindele ati oko e, Abdul-Rasheed-Bello a.ka. JJC Skillz ti won maa n
gbadun awon sinima e lolo-kan-o-jokan naa n ba a dupe lori ibeji ti Olorun sese
fun won.
Ninu oro Abiodun Kupoluyi, gbajumo akoroyin to n ri si iroyin
to ni se pelu Funke Akindele, lo ti so pe, loooto lawon molebi yii sese di
olomo tuntun, ati pe okunrin lanti-lanti meji ni won bi.
Ni bayii, o ti le ni atejise egberun kan aabo (1500) to ti
wa lori ero ayelujara e, ti awon eeyan fi n ki i ku oriire.
Odun yii gan-an ni Funke Akindele deni odun mokanlelogoji
(41), lodun 2012 lo ti koko segbeyawo, ti iyen si fori sanpon leyin osu merinla
to ti wa ninu igbeyawo ohun. Lodun 2016 lo rora segbeyawo bonkele pelu oko e,
Rasheed Bello, eni tawon eeyan tun mo si ni JJC Skilz, olorin ni, ilu London ni
won si ti se e jeeje.
Leyin igbeyawo won, lojiji lawon eeyan gbo pe Funke Akindele
loyun, bi won ti se n ba a jo, bee ni won n ba a yo pelu lasiko ohun, sugbon
sadeede ni iboosi tun gba igboro kan wi pe oyun ibeji to ni ti baje mo on lara.
Bi isele ohun se waye lawon wolii kan ti ko awon oniroyin
jo, ohun ti won si so ni pe yoo soro fun obinrin onitiata yii lati dolomo laye,
afi to ba fe eni to kere si i patapata, bee lo tun gbodo gbadura gidigidi ki o
ba le lomo laye.
Sa o, Olorun ti gbadura Funke, bee lawon omo Nigeria atawon
ololufe e kaakiri agbaye n ba a yo, ti won n ba a jo.




0 Comments