GBAJUMO

BASIRAT IYA-N-GHANA SOJOOBI L‘EKOO *E GBO AWON ASIRI NLA TO TU *BEE LAWON OSERE NLA NAA BA A DEBE

Pitimu loju pe, ti ese pele lagbegbe Capitol niluu Agege loni-in Wesde, ojo kesan-an odun tuntun yii nigba ti gbajumo olorin esin Islam nni, Basirat Ogunremi sojoobi e, ninu eyi tawon olorin egbe e ti wa, tawon ololufe e paapaa ko sai ko ipa ribiribi, atawon omo e paapaa, nibi ti gbogbo won ti seye nla fun un.

Bi awon omoose e ti won ti figba kan gberin leyin e naa se bo soju ogbagede lati korin fi saponle, bee lawon akegbe e, ti won wa nibe ko sai ba a dupe, wi pe obinrin naa tun lanfaani lati sajoyo ojoobi e loke eepe.
Ninu oro Alhaja Basirat Ogunremi, iyen Iya-n-Ghana lo ti so pe, “Bo tile je ojo ayo lo ye ki ojo oni je, sibe ojo kan ti mo maa n sunkun lopo igba ti mo ba ranti ohun ti oju iya mi ri ki n too le wa saye ni. Bi e ti se n wo mi yii, mi o sun mojumo, ekun ni mo sun titi ile fi mo Nitori bi e se n wo mi yii, odun meji aabo ni mo lo ninu iya mi, ki emi naa too le wa saye. Ni gbogbo ojo ni aanu iya mi maa n se mi, nitori mo maa n wo o wi pe, iru ipo wo ni iya yen le wa fun odun meji aabo pelu oyun ninu.
“Isele yen gan-an lo maa n pa mi lekun gan-an. Bi mo se wa yii, okunrin ni mi o, emi ki i se obinrin, e le ri mi pe sura obinrin ni mo gbe wa saye, sugbon okunrin ni mi; nitori eegun mesan-an ni Olorun fun mi, isowo korin mi, bii okunrin ni, bee lawon isesi mi mi-in, ti awon eeyan le maa ri, bi okunrin ni mo se maa n se.”
Nigba to n soro lori ohun ti oju e ti ri, Iya-n-Ghana so pe, “Mo le so pe latinu oyun ni mo ti n la orisirisi iriri aye bo. Gege bi mo se so saaju, osu mesan-an ni gbogbo omo maa n lo ninu iya won, sugbon odun meji aabo lemi lo. Won ni nigba ti won tun bimo tan, mi o tun ke, bee ni mama mi so fun mi pe, ti awon eeyan ba wa, ti won n so pe omo tuntun, won ni nise ni mo n woju kaluku bii eni pe mo n gbo ohun ti won n so.
“Latigba ti mo ti wa de ile aye ohun, mi o gbonju mo awon obi mi ni olowo ri, sugbon mo mo won gege bi wolii Olorun ti won maa n sin Olorun daadaa. Gbogbo ohun ti oju ri patapata gege bi talika Olorun ti awon obi mi n se, gbogbo e pata ni mo ko sinu America Experience, emi tawon obi maa n se wahala ki a too le jeun, emi
naa ni mo deni to lo n bimo si America, awa to pe je pe a ko ya ile gbe ki a ko lo jade ri pelu irorun, nise ni won maa le wa jade nigba ti a ko ba ri owo ile san. Emi naa ni mo wa deni to n ko ile igbalode, mo deni to n sun, to tun n yi ninu ola, ope nla ni mo da fun Olorun, nitori e lo fi je pe ni gbogbo ojoobi mi, nise ni mo n ronu ohun ti oju awon obi mi ti ri ati ipo ti Olorun fi mi si loni-in.
*Kin ni awon nnkan m-in ti Iya-n-Ghana tun so nipa awon obi e, e pade ekunrere alaye yii lori telifisan wa lori Youtube…. De.reportorial TV  awon isele ati iroyin gbamko-gbi ni o….








Post a Comment

0 Comments