GBAJUMO

WON NI ARA MC OLUOMO TI YA O *N LAWON EEYAN E BA N YO, TI WON N SEPE FAWON OTA E


Kaakiri ori ero ayelujara bii facebook, Instagram lawon eeyan gbajumo onimoto nni, Alhaaji Musiliu Akinsanya, eni tawon eeyan tun mo si MC Oluomo ti n fi idunnu won han bayii lori bi iku se ye lori okunrin naa, bo tile je pe won ti koko  n gbe e kiri wi pe iku ti pa a.
Okan lara awon eeyan to sunmo MC Oluomo daadaa, Alhaji Ganiyu Ayinde, eni tawon eeyan tun mo si Koko Zaria lo gbe iroyin ohun sori ikanni e, iyen Instagram page, ohun to si ko sibe ni pe MC Oluomo ti pada sile, iku kan bayii ko pa a bi won se n gbe e kiri.

Ninu oro e lo ti so, “Mo dupe lowo Olorun lori ohun to se ninu aye wa l’Osodi. E kaaro eyin ololufe mi nile loko ati nile okeere, Olorun yoo tubo maa nife eyin naa si i. Bakan naa, eyin ota, mo ki eyin naa o, ohun ti mo fe so fun ni pe, Oga mi ti de pada si Osodi o, lako lo si wa bii ibon, ko si nnkan bayii to se e. Gbogbo iroyin eleje tawon ota n gbe kiri wi pe Oga ti ku, iro ni o, Olorun ju eda lo, kinni kan bayii ko se oga tiwa o.
“Lagbara Olorun, MC Oluomo lo maa di alaga fun awa onimoto l’Ekoo laipe yii, ipo yen ti bo si i, o si ti debe, ati pe ko si ohun kan to le da a `duro. Emi ni tiyin ni tooto, Koko Zaria, American Boy, Owo ko egbin, eyin ota atawon abinu-eni, gbogbo yin pata e lo ku danu!”
Bo se ko oro ohun ree sori instagram page e, ti awon eeyan si n fi idunnu won han orisirisi lori bi ori se ko Alhaji Musiliu Akinsanya yo lowo ewu.

Yato si amugbelegbee okunrin onimoto yii, opolopo osere tiata atawon olorin ni won n gbe orisirisi oro jade, paapaa adura lati fi toro emi gigun fun Oluomo. Okan ninu won ni Alhaja Rodiya Sanni Adeboye, olorin Musulumi to n gbe ni Dublin, o fe ma si ojumo kan latigba tisele ohun ti waye, ki o ma sadura sori orisisisi ero ayara-bii-asa lati fi toro alaafia fun un.

Awon mi-in ti won tun pelu ninu igbese yii ninu awon osere nla nla ni Bimbo Akisanya, Mistura Aderohunmu, Alhaji Wasiu Alabi Pasuma, Kemi Korede atawon mi-in lorisirisi.
Tusde, ojo Isegun to koja ni wahala buruku be sile nibi tawon egbe oselu APC ti seto ifilole eto ipolongo ibo odun 2019 ni agbegbe kan niluu Ikeja l’Ekoo.
Rodiya Sanni, olorin Islam ni Dublin
Kaakiri gbogbo ijoba ibile lawon omo egbe oselu ohun ti wa lojo naa, nibe gan-an ni ija ti be sile laarin omo onimoto ti won ti ni ara won sinu, ki oloju si too se e, won ti gun MC Oluomo lobe nikun, won tun gun un lorun ati lowo.
Yato si MC Oluomo, enikan ti ibon ba nibi isele ohun ku lojiji, bee lawon oniroyin meta naa faragba ninu uisele ohun. Ibon lo ba won o, sugbon Olorun ko je ki won ku.
Bawon kan se n gbe e kiri wi pe awon eeyan Kunle Poly lo sise ohun, bee lawon mi-in tun n daruko Mustapha Sego, bee nileese olopaa ti kede wi pe awon n wa Mustapaha Sego bayii
  

Post a Comment

0 Comments