GBAJUMO

IJO CAC GOD OF FIRE FE SETO NLA L’EKOO *WON NI KI GBOGBO EEYAN WA GBA AANU TI KO LOPIN


Monde, ojo ketalelogbon osu yii ni ijo CAC GOD OF FIRE INTERNATIONAL yoo bere akanse eto olododun won, ti yoo si pari lojo Eti, ojo ketadinlogbon osu yii.
Ninu ileejosin ohun to wa ni the nonba 26, Unity avenue, Unity Bus stop, off Water Cooperation, Agbado, Adiyan, nipinle Ogun ni eto pataki ohun yoo ti waye.
Ohun ti won fi se akori ipago ti odun yii ni Aanu ti ko lopin (Unstoppable Mercy). Lara awon ojise Olorun ti yoo dari awon eeyan nilana ti emi nibi ipade ologo yii niwonyi; AP Michael Olubayo (Baba Fire), Pasito S.O Abatan, Pasito Gbenga Adedeji, Efanjeliisi B.O Itisiola (Olorun ina oo).
Awon olorin emi ti yoo forin igbala gbe eto ohun laruge ni; Efanjeliisi Funmi Anjolajesu ati akorin emi nni, Funmilayo Idowu.
Wolii Sam Itisiola eni tawon eeyan tun mo si Olorun ina ooo’ eni ti yoo gba awon eeyan lalejo nibi eto ohun ti so pe, “Gbogbo omo Olorun pata la ke si atawon eeyan kaakiri lati wa je anfaani nla yii. A fe ki won wa gba itusile, a fe ki won wa deni iselogo, bee ni aye won ko ni i ri bakan naa mo, nitori Olorun aanu; oba majeumu ni Oluwa ti awa n sin, ti ipinnu rere re lori wa ko ni i ye laelae.


Post a Comment

0 Comments