GBAJUMO

Olu Itori sọ̀rọ̀ s'áwọn tó ń gbé fídíò òun àti Gómìnà Dàpọ̀ Abíọ́dún Kiri, ó ní àìníṣẹ́ ló ń ṣe wọn o, tòun yé òun dáadáa


Lati bi ọjọ mẹta kan sẹyin ni awuyewuye n lọ laarin igboro nitori bi Olu tiluu Itori, Ọba Abdulfatai Akorede Akamọ ṣe kunlẹ niwaju Gomina Dapọ Abiọdun,nibi ayẹyẹ kan to waye laipẹ yii.

Ṣugbọn Kabiyesi ti sọrọ, o sọ pe ọrọ naa ko le ye awọn to n gbaa bi ẹni gba igba ọti, nitori alaanu ati oloore oun ni Gomina ati pe ka ni kọrọ lawọn ti pade, oun yoo ṣe ju bẹẹ lọ.


O sọ pe laye ode onii, ta ni  ko mọ pe ipo gomina ju ọba lọ, nitori awọn lo n fọwọ sii, ki eeyan to le jọba ati pe abẹ lawọn ọba ti n gbowo, nitori naa lo ṣe yẹ kawọn fi ọla fẹni to ba yẹ.


Ati pe idi toun fi ṣe bẹẹ lọjọ naa ni lati fi ẹmi imoore han si iṣẹ akanṣe ọna to ṣeleri pe oun yoo ṣe pe wọn ko ni pẹ bẹrẹ ẹ mọ.


Olu Itori ṣalaye siwaju pe,"Emi kọ ni mo sọ pe mo ni iroyin ayọ fun Gomina,nibi ti mo jokoo si lo ti sọ fun mi pe ki wọn pe mi, oun ni iroyin ayọ fun mi,nibi to jokoo si aye awọn gomina ni, ko si tọna fun mi lati jokoo sibẹ.


"Mo si ni lati bẹrẹ mọlẹ lati gbọ nnkan to n sọ nitori ariwo waa nibẹ.Igba ti wọn si maa sọrọ, wọn lawọn niroyin ayọ fun mi pe ọna marosẹ atijọ, wọn maa bẹrẹ ẹ laarin ọsẹ mẹta si akoko yii.


"Ati pe ọsibitu jẹnẹra to ti fẹẹ wo tan awọn yoo kọ, inu mi dun gan an ni ohun to ba si wu ẹlẹnu ni ko maa sọ, gbogbo eeyan lo ni anfaani lati sọ nnkan to ba wuu

   

"Ṣe ko to ọpẹ, gbogbo awọn to n gba oju ọna marosẹ agbegbe mi kọja ni wọn mọ pe ko dara rara, to si kọja sisọ, o si tipẹ taa ti n bẹbẹ fun atunṣe mo wa ri Gomina to fẹẹ ba mi ṣe, ẹ waa ni ki n ma ra baaba niwaju ẹ.


Olu Itori tun ṣapejuwe Gomina Dapọ Abiọdun gẹgẹ bi ẹni to mọ apọnle ọba, ti ko si fọrọ wọn ṣere. O waa ni oun ko kabamọ rara nitori oloore oun ni.


O waa pari ọrọ e pe ka ni akoko toun ba gomina sọrọ, oun duro,gomina jokoo, ọtọ ni ariwo ti wọn yoo ma pa. O ni oun ko ri tawọn to n sọ isọkusọ naa ro, bi ko ṣe bi ilu Itori yoo ṣe tẹsiwaju.

Post a Comment

0 Comments